Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn igbimọ agba ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, iyẹn Osun APC Elder’s Caucus, ti kede pe ki alaga ẹgbẹ naa nigba kan, Alagba Adelọwọ Adebiyi, lọọ rọọkun nile latari pe oun lo jẹ aṣiwaju ẹgbẹ kan to ṣẹṣẹ lalẹ hu ti wọn n pe ni The Osun Progressives.
Ẹgbẹ tuntun naa, eyi ti Minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, jẹ alaga igbimọ rẹ (Board of Trustees), ni awọn igbimọ agba sọ pe ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹ ni ko si bofin mu.
Lẹyin ipade oloṣooṣu wọn to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, labẹ idari Akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun nigba kan, Ẹnjinnia Ṣọla Akinwumi, ni wọn ti sọ pe awọn ko mọ ohunkohun to n jẹ TOP, bẹẹ ni wọn jẹjẹẹ atilẹyin wọn fun Gomina Adegboyega Oyetọla.
Wọn ni gbọingbọin lawọn duro ti awọn alakooso ẹgbẹ labẹ idari Ọmọọba Gboyega Famọdun ati pe mimi kan ko lee mi ijawe olubori Oyetọla fun saa keji nipo gomina Ọṣun.
Atẹjade naa sọ pe, “Igbimọ Agba Ọṣun ko fara mọ ifọrọwerọ ori redio kan ti Alagba Adelọwọ Adebiyi ṣe laipẹ yii nibi to ti n sọ pe iyapa inu ẹgbẹ APC l’Ọṣun lo ṣokunfa idasilẹ TOP, nitori naa, a paṣẹ pe ko lọọ rọọkun nile gẹgẹ bii ọkan lara wa.
“A ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wa lati ma ṣe ṣojo rara, ki wọn gbaruku ti ẹgbẹ, ki wọn duro ti ẹgbẹ, ki ẹgbẹ wa le gbooro si i. A dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn fun Gomina Isiaka Adegboyega Oyetọla lori oniruuru iṣẹ takuntakun to n ṣe lai fi ti owo perete to n wọle ṣe rara”