Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti fofin de ẹka iroyin ayelujara ti wọn n pe ni ‘Twitter’ bayii. Wọn ni eegun wọn ko gbọdọ ṣẹ lori afẹfẹ titi digba ti ko ni akoko kan.
Minisita fun eto eto iroyin ati irin ajo afẹ ni Naijiria, Alaaji Lai Mohammed, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa yii, l’Abuja.
Ninu atẹjade kan ti Ṣẹgun Adeyẹmi, Amugbalẹgbẹẹ pataki si Lai Muhammed buwọ lu, ṣalaye pe iṣekiṣẹ ni Tuita tawọn kan n pe ni Abẹyẹfo, n ṣe ni Naijiria.
Atẹjade naa sọ pe iṣe iroyin ti Tuita n ṣe le tu orilẹ-ede yii ka.
Bakan naa ni wọn ni awọn ti paṣẹ fun ileeṣẹ NBC to n ri si ohun to n jade lori afẹfẹ lorilẹ-ede yii lati ri i pe wọn n yẹ iṣẹ awọn ẹka ayelujara ti wọn n gbe iroyin jade bo ṣe n ṣẹlẹ wo, (OTT) kawọn naa le kọwọ ọmọ wọn bọṣọ.
Ẹ oo ranti pe Tuita pa ọrọ Aarẹ Buhari to sọ lori awọn IPOB to n ja fun BIAFRA rẹ, ọrọ rẹ meji ni wọn fa lulẹ loju opo naa, ti wọn ni o lewu kiru ẹ maa ti ẹnu olori ilu jade.
Ohun tawọn eeyan n sọ bayii ni pe igbesẹ Tuita lori Buhari lo fa ohun ti ileeṣẹ Aarẹ ṣe yii, wọn ni aye alabata nijọba yii n jẹ.