Olori ẹgbẹ to n ja fun ilẹ Yoruba ti wọn n pe ni Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti rọ awọn ọmọ Yoruba ki wọn ma sun asunpara, bẹẹ lo rọ awọn gomina ilẹ Yoruba pe ki wọn gbe ọrọ oṣelu tabi ofin tio wọn fi n ka wọn lọwọ ko ti sẹgbẹẹ kan, ki wọn mura lati daabo bo awọn eeyan wọn. Baba naa ni pẹlu ipaniyan to ṣẹlẹ niluu Igangan yii, o daju ṣaka pe ijọba apapọ, labẹ isakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ti dide ogun si ilẹ Yoruba bayii.
Ninu atẹjade kan ti baba naa fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo ti fẹsun kan ijọba Buhari pe o n gbe lẹyin awọn Fulani afẹmiṣofo to n pa awọn ọmọ Yoruba, ti wọn n fipa ba awọn obinrin wọn lo pọ, ti wọn si n ba dukia wọn jẹ.
Ọjọgbọn Akintoye waa rọ awọn ọmọ Yoruba pe ki wọn ta mọra, ki wọn ṣamulo ohunkohun ti wọn ba ni tabi ti wọn le dawọ le lati daabo bo ara wọn ati ilẹ wọn lọwọ awọn ajeji yii.
O gboriyin fun Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, fun bo ṣe dide akin lori pipa ti wọn pa awọn Yoruba niluu Igangan yii, o waa rọ awọn gomina ilẹ Yoruba pe ki gbogbo wọn pa ọrọ oṣelu tabi ẹgbẹ ti, ki wọn dide lati daabo bo awọn eeyan wọn. Akintoye ni ‘Wọn ti yi ilẹ Yoruba ka, a si gbọdọ dide bayii bayii.’
Ọjọgbọn Akintoye waa ke si awọn ọdọ ilẹ Yoruba pe ki wọn dide, ki wọn si mura giri, ki wọn jade lati daabo bo ilẹ baba wọn nipa ọnakọna ti ibaa jẹ, bo jẹ ti imọ ẹrọ, bo jẹ ti adayeba, bo si jẹ ti ki wọn koju awọn ẹni ibi naa ni. O ni wọn ko gbọdọ gba ikọlu awọn Fulani laaye lati bori ilẹ Yoruba.
Bakan naa lo ba awọn eeyan ilu Igangan kẹdun, o si ke si awọn ọmọ Yoruba nile-loko ati lẹyin odi pe ami buruku ni eyi to ṣelẹ yii, a ko si gbọdọ wo o niran rara.
Akintoye ni ‘Ijọba apapọ ti kuna patapata lati daabo bo ilẹ Yoruba pẹlu awọn ẹya Guusu atawọn Middle Belt ti awọn Fulani darandaran n yọ lẹnu.
Ti a ba wo iwa ati iha ti ijọba apapọ kọ si wahala buruku to n ṣelẹ ati awọn ewu to n mu wa fun awọn araalu tọrọ kan, ohun ti a le sọ naa ko ju pe o da bii pe ijọba apapọ gan-an lo n ṣatilẹyin fun awọn eeyan yii, awọn gan-an ni wọn ran wọn niṣẹ
‘Ijọba apapọ gba awọn eeyan yii laaye lati maa gbe awọn ibọn to lagbara kiri, bẹẹ ni wọn gba gbogbo ibọn ti awọn araalu fowo ara wọn ra ti wọn si gba iwe rẹ, wọn fofin de araalu lati ma ṣe lo ibọn.’
O fi asiko naa dupẹ lọwọ awọn ọdọ ti wọn dide lati ja fun ilẹ baba wọn, bẹẹ lo rọ wọn ki wọn ma ṣe kaaarẹ. O si rọ awọn ọmọ Yoruba lati ṣatilẹyin fun awọn eeyan yii.