Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ baba agba ẹni aadọta ọdun kan, Adewunmi Gbadamọsi, lori ẹsun pe o yinbọn pa ọmọkunrin kan, o si ge ẹya ara rẹ si wẹwẹ.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ṣe ṣalaye fawọn oniroyin nigba to n ṣafihan awọn afurasi naa, o ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni ọwọ tẹ Gbadamọsi atawọn ti wọn jọ ṣiṣẹ naa.
Ọlọkọde sọ pe wọn ka ọwọ {hands} meji ati ẹsẹ meji to ti n jẹra mọ Gbadamọsi to n gbe lagbegbe Oke-Ayepe, niluu Oṣogbo, lọwọ, o si ti jẹwọ pe Pasitọ Ọlagunju Adetunji to n gbe ni Kajọla Ileṣa loun gbe ori ọmọ naa fun.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Gbadamọsi ṣalaye pe “Iṣẹ awakọ ni mo kọkọ n ṣe nibẹrẹ aye mi, ṣugbọn nigba ti n kan ko lọ deede mọ ni mo pada sidii iṣẹ ọlọdẹ ti baba mi naa ṣe to fi ku.
“Adugbo Tara, niluu Oṣogbo, ni wọn gba mi pe ki n maa ṣọ. Lọjọ iṣẹlẹ yii, ṣe lọmọ naa fẹẹ fo fẹnsi wọnu ile onile, nigba ti mo ka a mọbẹ, mo beere ibi to ti n bọ, ko sọrọ, mo beere orukọ rẹ, o ni Kehinde ni.
“Bo ṣe fẹẹ maa sa lọ niyẹn, ni mo ba yinbọn lu u, lo ba ṣubu lulẹ, nigba ti mo sun mọ ọn ni mo ri i pe o ti ku. Ẹru ba mi, n ko mọ nnkan ti mo le ṣe, ki aṣiri ma baa tu, mo fi ada ge ori rẹ nitori n ko le da a gbe sinu igbo.
“Mo ge ori ẹ, mo ge ọwọ rẹ mejeeji ati itan rẹ mejeeji, mo waa sọ ogulutu ara rẹ sinu odo Ọkọọkọ. Ọrẹ mi kan to n ṣiṣẹ riwaya lo sọ fun mi pe Pasitọ Ọlagunju nilo ori eeyan.
“Bayii lemi ati ọrẹ mi gbe ori ọmọ naa lọ sọdọ pasitọ ni Kajọla, nigba ti a debẹ, o ni loootọ loun nilo oju (eyes) ṣugbọn oun ko ni owo toun fi le ra ori afi ti mo ba maa gbe e fun oun lọfẹẹ, mo si gbe e fun un lai gba owo kankan.
“Bi aṣiri ṣe waa tu bayii, ti wọn fi waa mu mi lonii ko ye mi rara, mo jẹun tan lẹyin ti mo de lati oko ni awọn ọlọpaa wọle wa mu mi”.
Ni ti Pasitọ Ọlagunju, o ni pasitọ ijọ Kerubu ati Serafu loun, oun si ti n ṣiṣẹ Ọlọrun tipẹ. O ni loootọ loun maa n ṣeto adura fawọn alaisan tabi ẹnikẹni to ba niṣoro, ṣugbọn oun ki i lo ẹran ara eeyab tabi ẹjẹ.
O ni irọ patapata ni Ọgbẹni Gbadamọsi pa mọ oun nitori ko gbe ori-eeyan kankan wa ba oun ri, igba keji si leleyii ti oun yoo foju kan an ri laye.
O fi kun ọrọ rẹ pe ẹnikan to riwosan nipasẹ oun lo mu Gbadamọsi wa sọdọ oun, oun si ṣadura fun un lai sọ fun un pe ko mu ohunkohun wa.
Bakan naa ni ọwọ tẹ Rasheed Ajani, ẹni ọdun marundinlọgọta, Saka Akeem, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati Abiọdun Adetimilẹhin toun naa jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta lori iṣẹlẹ naa.
Ọlọkọde waa ṣeleri pe ni kete tiwadii ba ti pari lori awọn afurasi naa ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.