Lẹyin to ti bibeji, ẹ wo obinrin to bimọ mẹwaa lẹẹkan naa

Iṣẹ Ọlọrun ọga ogo ko ṣee tu, aṣiri iṣẹda ko yeeyan, Ọlọrun nikan lo ye. Obinrin ti inu rẹ fẹrẹ le maa kan an lẹnu yii ti bi ibeji tẹlẹ, lọjọ Mọnde, ọjọ keje, oṣu kẹfa yii, lo tun bi ibẹwaa. Gosiame Thamara Sithole lobinrin naa to bimọ ọkunrin meje, obinrin mẹta lẹẹkan ṣoṣo!

Orilẹ-ede South Africa lobinrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji yii n gbe pẹlu ọkọ rẹ torukọ tiẹ n jẹ Teboho Tsotetsi. Ọkọ yii ko tilẹ niṣẹ kankan lọwọ lasiko tiyawo rẹ bi ibẹwaa yii, ṣugbọn niṣe ni inu rẹ n dun sẹnkẹn, ohun to si sọ fawọn akọroyin ni pe ayanfẹ Ọlọrun loun pẹlu oore nla to ṣe foun yii.

Iya to bimọ mẹwaa yii paapaa ko mọ pe awọn ọmọ to wa nikun oun pọ to bẹẹ, o loun ro pe mẹjọ ni wọn ni, pẹlu ayẹwo. Ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ si i fi iṣẹ abẹ gbe wọn jade nikọọkan ejeeji, ti ọmọ mẹwaa balẹ gudẹ koloju too ṣẹ ẹ, nigba naa ni Gosaiame mọ pe boun ti ro o kọ lori.

Iya ibẹwaa yii waa sọ kinni kan o, o loun ko lo oogun oyun nini koun too loyun awọn ọmọ yii. O ni ki i ṣe ilana IVF ti wọn fi n bi ibeji, ibẹta tabi ju bẹẹ lọ loun lo, o lo wu Ọlọrun loke lo fi awọn ọmọkunrin meje ati obinrin mẹta sinu oun lẹẹkan ṣoṣo.

Lagbaaye bayii, Gosiame yii lorukọ rẹ wa ninu itan gẹgẹ bii ẹni to kọkọ bi ibẹwaa. ‘Decuplets’ loyinbo n pe ọmọ mẹwaa lẹẹkan ṣoṣo.

Obinrin ara Malia kan, Halima Cisse, lo gbade ọlọmọ mẹsan-an lẹẹkan ṣoṣo loṣu to kọja, ti wọn ni ko ti i si ẹni to bi ibẹsan-an ninu iwe itan agbaye. Ṣugbọn ni bayii, Gosiame to bi mẹwaa yii lorukọ rẹ ṣi n rin kari aye, gẹgẹ bii abiyamọ to bimọ mẹwaa lẹẹkan ṣoṣo.

Leave a Reply