Kawọn gomina lọọ yanju eto aabo ipinlẹ wọn, ki wọn yee di gbogbo ẹru le mi lori – Buhari

 L’Ọjọbọ, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun 2021 yii, ni Aarẹ orilẹ-ede wa, Muhammadu Buhari, han lori tẹlifiṣan kan ti wọn n pe ni ‘Arise’. Nibẹ lo ti fi idaniloju sọ pe ẹnikẹni to ba fẹẹ di aarẹ Naijiria lọdun 2023 ni lati darapọ mọ ẹgbẹ APC, nitori ẹgbẹ naa ni yoo maa ṣejọba orilẹ-ede yii lọ lẹyin oun.

Aarẹ Buhari ko deede sọrọ yii, nigba to n dahun awọn ibeere ti atọkun eto naa n ti si i nipa Naijiria ti ko toro lasiko yii ni Aarẹ sọ pe ẹgbẹ APC ni yoo maa tukọ Naijiria lọ lẹyin oun.

Ṣaaju ni Buhari ti kọkọ fi ibinu rẹ han si eto aabo to mẹhẹ tawọn eeyan n pariwo rẹ lasiko yii. O ni awọn gomina ilẹ Yoruba lo wa nibẹ yẹn ti awọn araalu dibo fun wọn tan ti wọn ko le lo agbara to wa nikaapa wọn lati daabo bo awọn eeyan wọn.

Aarẹ sọ pe awọn gomina ilẹ Yoruba meji waa ba oun l’Abuja, wọn waa fẹjọ awọn Fulani sun, pe awọn agbẹ sọ pe Fulani n ba oko awọn jẹ. Buhari loun bi awọn gomina naa leere pe ki lo ṣẹlẹ sawọn alaabo ibilẹ wọn, bẹrẹ latori awọn ọba, titi de ori awọn ijọba ibilẹ to jẹ wọn n ṣepade loorekoore lati mọ hulẹhulẹ iṣoro wọn ati ibi ti awọn oniṣẹ ibi n wọlẹ si ni agbegbe wọn, ki wọn si mu wọn. O loun beere pe ta lo ba eto gbogbo nilẹ yii jẹ, ki wọn pada sile, ki wọn lọọ tun un to.

Nitori oun koriira keeyan fi ojuṣe rẹ silẹ, ko maa sunkun ẹlẹya kiri, ko maa wa ẹni ti yoo ba a ṣe e nigba to ni agbara lati ṣe nnkan rẹ funra rẹ.

‘‘Mi o nifẹẹ si keeyan polongo ibo pe ki wọn dibo foun lati di gomina, ki wọn dibo naa fun un tan, ko ma le ṣe ojuṣe rẹ fun wọn. Niṣe ni wọn fẹẹ ti ohun to jẹ iṣẹ wọn sawọn eeyan mi-in.

‘‘Ẹka iṣejọba mẹta la ni, ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ. A ti pa ijọba ibilẹ ku patapata. Ijọba apapọ yoo fi ọọdunrun miliọnu ranṣẹ sijọba ibilẹ gẹgẹ bii owo to tọ si wọn, gomina kan yoo gba a, yoo ni ki alaga ijọba ibilẹ kọwọ bọwe pe oun ti gba gbogbo ọọdunrun miliọnu naa, ko si ni i fun un ju ọgọrun-un kan miliọnu lọ. Alaga naa yoo gba a, ko ni i wi nnkan kan. Ṣe ba a oo ṣe maa ba a lọ niyẹn.’’ Bẹẹ ni Buhari beere lai reti esi lọdọ ẹnikan.

Aarẹ ko ti i dakẹ, o tun sọrọ nipa pinpin ipo olori lẹnu iṣẹ ologun, eyi tawọn eeyan n sọ pe o fi si apa ibi kan ju ibi kan lọ. Buhari ni ko si bi ko ṣe ni i ri bẹẹ, nitori ẹni to ti gba ẹkọ lẹnu iṣẹ ọlọpaa ati ti ologun, to mọ apade-alude iṣẹ naa loun yoo fi sibẹ, ki i ṣe ẹya ti ẹni naa jẹ lo ṣe koko.

O fi kun un pe ẹya ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu iṣẹ ati ipo ologun, nitori wọn ko fi ti ẹya ṣe ki wọn too gbaayan sibẹ. O lẹni to ba wu lati darapọ lo n di ṣọja tabi ọlọpaa, ẹni ti ko ba darapọ, ko sẹni ti yoo mu un pe ko ṣe bawọn kọṣẹ ologun. Ṣugbọn ti wọn ba n pin ipo olori, ki ẹni ti ko kẹkọọ debi ti yoo fi dọga ma sọrọ, ẹni ti ẹya rẹ ko si bawọn kẹkọọ to ko gbọdọ sọ pe wọn ko pin in daadaa.

Nipa iṣẹ ti ko si ni Naijiria, ti awọn ọdọ to kawe ko ribi kan gba lọ. Aarẹ sọ pe awọn ọdọ naa lo fa a. O ni nigba to jẹ jagijagan ni wọn n ṣe. O ṣakawe rogbodiyan to waye nigba END SARS, ti wọn jo ọpọlọpọ mọto BRT nina l’Ekoo. Buhari sọ pe ta ni yoo gbọ iru iroyin bẹẹ ti yoo ti ilẹ okeere waa daṣẹ silẹ ni Naijiria, o lohun to n fa wahala sọrun awọn ọdọ niyẹn. Bi wọn ba fẹ kiṣẹ wa, ki ara si rọ wọn, Buhari ni kawọn ọdọ fọwọ sibi tọwọ n gbe ni.

Ko ṣai dahun ibeere ti wọn bi i nipa awọn IPOB, iyẹn awọn ẹya Ibo ti wọn n beere fun Orilẹ-ede Biafra. Aarẹ ni oun ti sọ fawọn ṣọja atawọn ọlọpaa pe ki wọn fi ọwọ lile mu wọn. O loun ko kabaamọ ohun toun sọ tẹlẹ nipa wọn rara, awọn ọlọpaa ati ṣọja ni yoo kapa wọn ni tiwọn.

Nipa pinpin Naijiria tawọn ẹya n beere fun bayii, Buhari sọ pe apẹẹrẹ buruku ni, ko si ni i jẹ kawọn olokoowo waa daṣẹ silẹ ni Naijiria.

‘Ṣe orilẹ-ede kọọkan ta a ba da silẹ yoo di paradise ni? Bawo la ṣe fẹẹ pin awọn nnkan to da wa pọ? Awọn ohun ta a ti jọ ṣe nigba ta a ti wa papọ. O ya mi lẹnu pe awọn ọmọwe lorilẹ-ede yii tun n ba awọn eeyan yii sọ ọrọ arufin yii. Ta a ba wa papọ bii Naijiria lo daa ju fun wa’’ Bẹẹ ni Buhari wi, to si fi ifọkanbalẹ pari rẹ pe APC ni yoo maa ṣejọba Naijiria lọ lẹyin oun

 

Leave a Reply