Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti wọn gba foonu ati gbogbo owo to wa lọwọ ẹ, awọn adigunjale yinbọn pa akẹkọọ Poli Ibadan kan, Ebenezer Ayẹni.
O ku ọjọ mẹsan-an ti ọkunrin yii yoo ṣegbeyawo ni wọn da ẹmi ẹ legbodo, nitori ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to n bọ, ni wọn lọkunrin naa iba ṣegbeyawo.
Laduugbo Ọjọọ, n’Ibadan, ni wọn ti da ọmọkunrin to lẹbun orin kikọ daadaa naa lọna l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ẹruuku ti sun mọ ọn daadaa ki wọn too yinbọn fun un nigbaaya lẹyin ti wọn gba gbogbo nnkan ti wọn ba lọwọ ẹ tan.
Bi arẹwa ọkunrin yii ba tete rẹni tọju ẹ, boya iba ru u la, ṣugbọn niṣe lawọn dokita ileewosan UCH, n’Ibadan, faake kọri pe dandan ni ki awọn ri iwe-ẹri latọdọ awọn ọlọpaa, lati le ri aridaju pe ki i ṣe oko ole ni wọn ti yinbọn mọ ọn ki awọn too le tọju ẹ.
Akẹkọọ ileewe Poli Ibadan ni wọn pe Ebenezer, ọdun yii ni iba kẹkọọ gboye jade nileewe naa nitori akẹkọọ ọlọdun keji nipele ikẹkọọ-gboye giga lo jẹ lẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ orin kikọ.
Gbogbo awọn to mọ oloogbe yii nigba aye ẹ ni wọn ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii eeyan to labuda ọjọ iwaju rere lara.
Yatọ si bi Ọlọrun ṣe fun un lẹbun orin kikọ to bẹẹ to tun maa n kọ awọn eeyan niṣẹ ọhun, ọkunrin yii tun ti ni ileeṣẹ ipese orin to ti n gbe awo orin awọn olorin jade.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, pẹlu Alhaji Ṣọladoye Adewọle ti i ṣe agbẹnusọ fún ileewe Poli Ibadan fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.