Ọlawale Ajao, Ibadan
Itankalẹ kokoro arun Korona tun bọna mi-in yọ lanaa pẹlu bi awọn dokita, nọọsi atawọn oṣiṣẹ ileewosan ijọba Jericho Specialist Hospital, n’Ibadan, ṣe fara kaaṣa ajakalẹ arun naa.
Alamoojuto fun awọn iṣẹlẹ to ba ni i ṣe pẹlu ọrọ ajakalẹ arun nipinlẹ Ọyọ, Dokita Taiwo Ladipọ, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin lanaa. O ni awọn kan ninu awọn dokita atawọn nọọsi to n tọju awọn alaisan nileewosan Jericho ti lugbadi arun Korona o.
Ba a ṣe n wi yii, awọn dokita atawọn nọọsi tọrọ ọhun kan ti wa ni ifarapamọ bayii, wọn si ti ti abala ileewosan ọhun kan pa.
Gẹgẹ bo ṣe fidi ẹ mulẹ, Dokita Ladipọ ṣalaye pe “Ọkan ninu awọn alarun Korona la n tọju nileewosan yii ti kokoro naa fi ran awọn dokita to n tọju ẹ pẹlu awọn nọọsi to ti ni nnkan kan tabi ekeji i ṣe pẹlu ẹni yẹn.
“Bi esi ayẹwo yẹn ṣe jade, to fidi ẹ mulẹ pe awọn dokita atawọn nọọsi yẹn ti fara ko kokoro arun Korona la ti ti ẹka ti wọn ti n ṣiṣẹ pa ko ma di pe ajakalẹ arun yẹn maa ran de awọn ẹka yooku naa.’’