Bamgboye ku lojiji nitori jibiti miliọnu marun-un ti Peter lu oun atiyawo ẹ l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Peter Gbese, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), ki i ṣe ọmọ Naijiria, ilẹ Olominira Benin ni wọn ti bi i. Ṣugbọn o ti ilu naa waa ṣe gbaju-ẹ miliọnu marun-un naira fawọn tọkọ-taya Alao Bamgboye tawọn jẹ ọmọ orilẹ-ede yii, ti wọn si n gbe niluu Abẹokuta.

Peter lẹyin tọwọ tẹ ẹ

Ọrọ ti bọ sori tan ki aṣiri yii too tu, nitori Ọgbẹni Alao Bamgboye ko tilẹ si laye mọ ni tiẹ, jibiti ti Peter lu u lo ko ẹmi ẹ soke, to fi di pe ọkunrin naa ku iku ojiji.

Iyawo rẹ lo ṣẹṣẹ lọọ ṣalaye ni teṣan ọlọpaa Sabo, pe ọdun karun-un ree toun atọkọ oun ti mọ Peter Gbese. O ni latigba naa lo ti n tu awọn jẹ bii iṣu, to n gbowo lọwọ awọn nitori ajalu kan to ni yoo ja lu awọn pẹlu awọn ọmọ awọn bawọn ko ba tete mu owo wa fun iṣẹ kan toun yoo ṣe lati mu wahala naa kuro.

Obinrin naa sọ fawọn ọlọpaa pe ẹru ohun to ni yoo ṣẹlẹ naa lo ba oun atọkọ oun tawọn fi n fun un lowo naa diẹdiẹ titi ti miliọnu marun-un fi pe ṣangiliti. O ni Gbese mu awọn lọ si Benin, o gbe posi kan fawọn pe oun atọkọ oun ko gbọdọ ṣi i boun ko ba paṣẹ bẹẹ fawọn, n lawọn ba n tọju posi naa bii ọmọ.

Nigba ti oye yoo fi ye idile naa pe gbaju-ẹ nla ni Peter ṣe fun wọn, ko si kinni kan ti wọn le ṣe si i mọ, ọkunrin naa ti fowo wọn kọle si Benin, o si ti fi eyi to ku ṣe faaji gẹgẹ boun funra ẹ ṣe sọ.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti sọ ọ di mimọ pe ifisun Abilekọ Bamgboye lo jẹ ki teṣan ọlọpaa dọdẹ Gbese to ko tọkọ-taya si gbese ati iku ojiji yii, wọn si mu un lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, to ṣẹṣẹ pari yii.

Gbese funra ẹ jẹwọ pe oun loun lu wọn ni jibiti, o ni ṣugbọn miliọnu mẹta aabọ naira loun gba lọwọ wọn, ki i ṣe marun-un, o ni ile loun fowo naa kọ siluu awọn.

Posi to gbe fun wọn, aṣọ funfun, iwo ẹran ti wọn fi aṣọ funfun we ati ilẹkẹ lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ ẹ, CP Edward Ajogun si ti ni ki wọn mu un lọ sẹka itọpinpin iwa ọdaran ko si de kootu laipẹ.

  

Leave a Reply