Awọn agbebọn tun ji akẹkọọ-binrin rẹpẹtẹ gbe nileewe ijọba ni Kebbi

Faith Adebọla

Afi bii atẹgun to ja kiri ilu, bẹẹ lọrọ awọn janduku afẹmiṣofo agbebọn to n ṣoro bii agbọn nilẹ wa lasiko yii, wọn tun ti gbe wahala wọn de ipinlẹ Kebbi, awọn akẹkọọ-binrin ileewe ijọba tẹnikẹni ko ti i mọ iye wọn ni wọn lọọ ji gbe lafẹmọju Ọjọbọ, Tọsidee, yii.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, wọn ni niṣe lawọn agbebọn naa ya bo ọgba ileewe kọlẹẹji tijọba apapọ, Federal Government Girls College, to wa niluu Birnin Yauri, nijọba ibilẹ Yauri, nipinlẹ Kebbi, ni nnkan bii aago meji kọja iṣẹju diẹ lọganjọ oru.

Kidaa awọn akẹkọọ-binrin ni wọn n kawe nileewe naa, inu ọgba ileewe ọhun si ni wọn n gbe pẹlu awọn olukọ wọn ti wọn n gbe ile ijọba.

Ọkan ninu awọn ẹṣọ to raaye sa lọ ṣalaye pe ọkada rẹpẹtẹ lawọn janduku naa gun wa, ki ẹnikẹni too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ, o ni wọn ṣina ibọn bolẹ to fi jẹ pe oju oogun leeyan maa ro pe oun wa ni, o ni ibọn ni wọn fi ja geeti ileewe naa, ti wọn si rọ wọle.

O lawọn kan lara wọn wọ aṣọ ọlọpaa, ti wọn mura bii agbofinro. O ni niṣe ni wọn dẹnu ibọn kọ ekeji oun tawọn jọ n ṣe sikiọriti, ti wọn si fipa mu un pe ko mu awọn lọ sibi tawọn akẹkọọ-binrin naa n sun si.

Ọkunrin naa ni laarin ọgbọn iṣẹju, wọn ti ji ọpọ awọn akẹkọọ-binrin gbe, wọn ko wọn sori ọkada, wọn si gbe wọn wọgbo lọ.

Iroyin mi-in sọ pe awọn agbebọn naa yinbọn ba agbofinro kan to n ṣọ ọgba ileewe naa ki wọn too raaye wọle lọọ ṣiṣẹẹbi wọn, ṣugbọn wọn lọlọọpa naa ko ku.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi, DSP Nafiu Abubakar, sọ fawọn oniroyin lori foonu pe awọn ṣi n wadii ọrọ ọhun lọwọ, oun o ti i le sọrọ nipa ẹ bo tilẹ jẹ pe iroyin iṣẹlẹ naa ti to awọn leti.

Leave a Reply