Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkunrin kan, Kayọde Ogundele, ẹni ọdun marundinlaaadọrin, to n ṣiṣẹ kafinta niluu Ayetoro-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Ọsin, nipinlẹ Ekiti, ti wa ni akata awọn ọlọpaa ipinlẹ naa bayii pẹlu ẹsun pe o fi agidi ba iyawo baba rẹ to jẹ ẹni ọdun marunlelọgọrin (85) lo pọ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutuṣe, sọ pe Kayọde to jẹ ọmọ bibi ilu Ayetoro-Ekiti wọle lọọ ba iyawo baba rẹ yii ni deede agogo mẹjọ alẹ Ọjọbọ,Tọsidee, lati lọọ ba a fi oogun ibilẹ si ẹsẹ kan to fi ṣeṣe ni nnkan bii ọjọ meji sẹyin.
Wọn fi kun un pe lojiji ni Kayọde to wa lakata ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bayii ṣadeede ki iya arugbo to tun jẹ iyawo baba rẹ yii mọlẹ ni kete to ba a fi ogun si ẹsẹ rẹ yii tan.
Eyi lo fa a ti iya arugbo yii ṣe figbe ta pe kawọn araadugbo gba oun, o si bu ọkunrin naa so.
Nigba tawọn araadugbo de, wọn ba Kayọde nihooho, nibi to ti n ba iya yii lo pọ, loju-ẹsẹ si ni wọn ti mu un, ti wọn si fa a le ọlọpaa to wa ni ilu Ido-Ekiti lọwọ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Tunde Mọbayọ, sọ pe afurasi ọdaran naa ti wa ni atimọle awọn ọlọpaa, o ni awọn ti bẹrẹ iwadii to daju lori ọrọ naa.
Komiṣanna yii fi kun un pe wọn yoo gbe Kayọde lọ sile-ẹjọ ni kete ti wọn ba ti pari iwadii.