Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọsan-an oni yii ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ yii, eeyan mẹta lo doloogbe loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan. Ọkọ akero Mazda kan ni taya rẹ fọ lojiji, bi mọto naa ṣe gbokiti niyẹn, to di pe ọmọ irinsẹ, ọmọ ọdun mẹfa kan ati agbalagba obinrin kan jade laye.
Ipinlẹ Kwara ni mọto naa ti nọmba ẹ jẹ FUF 109 ZD ti n bọ gẹgẹ bi Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi ṣe ṣalaye fun ALAROYE.
Nigba to de agbegbe Youth Camp, ni nnkan bii aago meji kọja iṣẹju marun-un ni taya ọkọ naa fọ lori ere, eyi to fa ki mọto ọhun bẹrẹ si i gbokiti, asiko naa leeyan mẹfa fara pa, ti eeyan mẹta si ku.
Ileegbokuu-si Fakọya, ni Ṣagamu, ni Akinbiyi sọ pe awọn yoo ko awọn oku naa lọ, nigba ti awọn to ṣeṣe ti n gba itọju ni ọsibitu Idera.