Ṣe ẹ ranti Ọnarebu Farouk Lawan, aṣoju-ṣofin ilẹ wa tẹlẹ ri lati ipinlẹ Kano fun saa mẹrin, to jẹ alaga igbimọ to ṣewadii ẹsun owo iranwọ ori epo rọbi tijọba apapọ n san fawọn kọngila lọdun 2012, iyẹn (Committee on Petroleum Subsidy Regime) nile aṣoju-ṣofin naa, ọkunrin ọhun ti rẹwọn ọlọjọ gbọọrọ he bayii, latari bile-ẹjọ giga Abuja kan ṣe ran an lẹwọn ọdun mọkandinlogun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, wọn lo jẹbi gbigba owo abẹtẹlẹ lọwọ gbajugbaja oniṣowo epo nni, Fẹmi Ọtẹdọla.
Miliọnu mẹta owo dọla nile-ẹjọ fidi ẹ mulẹ pe Farouk beere pe ki wọn san foun gẹgẹ bii abẹtẹlẹ, ṣugbọn ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla ($500,000) lo kọkọ gba lẹyin idunaa dura, eyi lo mu ki Adajọ-binrin Angela Otaluka tile-ẹjọ giga to fikalẹ sagbegbe Apo, l’Abuja, ni ko lọọ fẹwọn jura lori ajere iwa ibajẹ to ṣi mọ ọn lori yii.
Ajọ ICPC to jẹ tijọba apapọ, to n gbogun ti iwa ibajẹ ati gbigba abẹtẹlẹ (Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission) lo wọ aṣofin to ti fọdun mẹrindinlogun ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Bagwai/Shanono, nipinlẹ Kano, naa lọọ ile-ẹjọ lọdun 2013.
Ninu alaye ti ICPC ṣe nile-ẹjọ naa, wọn ni Farouk ni ki ileeṣẹ Zenon Petroleum and Gas Limited, to jẹ ti Ọgbẹni Fẹmi Ọtẹdọla foun lowo abẹtẹlẹ miliọnu mẹta dọla, ki oun le ba wọn yọ orukọ ileeṣẹ Fẹmi Ọtẹdọla ọhun kuro lara awọn ileeṣẹ ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣe abosi lori ẹkunwo owo-ori epo tawọn eleebo n pe ni Petroleum Subsidy eyi tijọba apapọ n san fawọn olokoowo to n gba kọntiraati gbigbe epo rọbi nigba naa lọhun-un.
Wọn ni lẹyin ti wọn ti jọ sọrọ, ọkunrin naa gba okoolelẹgbẹta owo dọla ($620,000), bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla ($500,000) lẹri wa pe o bọ si i lapo ninu owo to beere fun ọhun. Ṣugbọn ohun ti ọdaran yii ko mọ ni pe Fẹmi Ọtẹdọla ti ta awọn ileeṣẹ otẹlẹmuyẹ lolobo lori ọrọ ọhun, ti wọn si ti sami si owo dọla ti wọn fẹẹ ko fun un, wọn ti kọ nọmba gbogbo ẹ silẹ, ki wọn le lo o gẹgẹ bii ẹri ati ẹsibiiti lọjọ iwaju, wọn ni wọn tun ya fidio owo gọbọi naa.
Lẹyin to gba abẹtẹlẹ naa tan lakara tu sepo, tọrọ si di ti ile-ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe Farouk loun ko jẹbi.
Lara ẹsun mẹta ti wọn ka si i lẹsẹ ninu iwe ẹsun ti nọmba rẹ jẹ FCT/HR/CR/76/13, Adajọ-binrin Angẹla ni ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ ohun ṣe kedere, ko si ruju rara pe loootọ lọkunrin naa gba abẹtẹlẹ o si jẹbi iwa ibajẹ ati ijẹkujẹ.
Adajọ naa ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun meje lori ẹsun ki-in-ni ati ekeji, ẹwọn ọdun marun-un ni ti ẹkẹta, aropọ gbogbo rẹ si jẹ ẹwọn ọdun mọkandinlogun, ṣugbọn wọn ni yoo ṣewọn naa papọ ni, to tumọ si pe ọdun meje ni yoo lọ.
Angẹla ni idajọ yii yoo jẹ arikọgbọn fawọn ti wọn ba n lo ipo ati anfaani ti wọn nipo oṣelu lati maa fi jẹ ijẹkujẹ ati gbigba owo aitọ.