Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ Majisreeti kan to fi ilu Ado-Ekiti ṣe ibujokoo ti ni ki Durodọla Kayọde, ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ati Ọwajulu Tobi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, maa lọ sẹwọn fun igba kan na.
Ninu ẹsun ọtọọtọ ti wọn fi kan awọn mejeeji, Durodọla Kayọde ni wọn fẹsun kan pe o fipa ba iya arugbo ẹni ọdun mẹrinlelogoji to jẹ iyawo baba rẹ laṣepọ pẹlu ipa, ni Ayetoro-Ekiti to wa nijọba ibilẹ Ido/Ọsin, nipinlẹ Ekiti.
Owajulu Tobi to n ṣiṣẹ kafinta niluu Emure-Ekiti ni tiẹ, ladajọ ni oun naa tun fipa ba ọmọdebinrin kan to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo pọ niluu Emure-Ekiti kan naa.
Ṣaaju ni ọlọpaa to n ṣoju ijọba, Inspẹkitọ Adejare Elijah, ti sọ pe oun ti ṣetan lati pe awọn ẹlẹrii meji-meji ọtọọtọ wa sile-ẹjọ naa lati waa jẹrii lori ipejọ naa. Ṣugbọn oun fẹẹ tọrọ aaye ranpẹ lọwọ ile-ẹjọ naa ki oun le fi akoko naa ko awọn ẹlẹri oun jọ. O tun ni oun yoo fi iwe ipẹjọ naa ranṣẹ si ileeṣẹ to n ṣeto ipẹjọ nileṣẹ awọn aṣofin ipinlẹ naa, koun le gba esi to daju lori ẹsun naa.
Inspẹkitọ yii tun fi kun un pe eleyii yoo fun oun ni aaye lati ko awọn ẹlẹrii oun jọ, ati lati le ko wọn wa si ile-ẹjọ naa lati waa fi ẹri to daju mulẹ lori ẹsun naa.
O ṣalaye pe awọn ọdaran naa ṣẹ ẹṣẹ yii lọjọ kẹtala ati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kefa, ọdun 2021, pẹlu bi awọn mejeeji ṣe fipa ba awọn obinrin mejeeji ọtọọtọ lo pọ. Ẹsun yii ni agbefọba ni o lodi si ofin ọtalelọọọdunrun o din meji ti ọdun 2012 ti ipinle Ekiti n lo.
Ninu idajọ rẹ, adajọ ile-ọjọ naa, Mohammed Salau, fọwọ si ẹbẹ olupẹjọ yii, o si paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọdaran mejeeji naa lọ si ọgba ẹwọn.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun yii.