Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Gomina Abdulrasaq Abdulrahman, fi mọto ayọkẹlẹ Salon mẹwaa, Toyota Hilux mẹwaa ati aṣọ akọtami ( bulletproof) ta ikọ alaabo ọlọpaa ati Harmony lọrẹ, lati gbogun ti iwa ọdaran ati ki ipinlẹ Kwara le wa ni alaafia.
Gomina ni oun gbe igbeṣẹ yii lati mu ki iṣẹ rọrun fun wọn ni ṣiṣe. O tẹsiwaju pe loootọ ijọba apapọ n ṣe bẹbẹ lori ọrọ eto aabo, sugbọn awọn gomina naa gbọdọ ko ipa tiwọn lati ran awọn ikọ alaabo lọwọ. O ni lọdun to kọja loun gbe ọkọ fun wọn, sugbọn ko tan sibẹ, isejọba oun yoo tun maa tẹsiwaju lati peṣe ohun eelo fun wọn ki iṣẹ wọn le ja gaara.
Gomina waa dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ọhun pẹlu bi wọn ko ṣe sun, ti wọn o wo, lati ri i pe ipinlẹ Kwara wa ninu aabo to peye, o ni oun woye pe ayipada rere ti de ba eto aabo nipinlẹ Kwara bayii, ki wọn tẹsiwaju nibi iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe, eyi ti oun ṣe lonii, aṣeyọri kan ni lati mu eto aabo gbopọn si i.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Mohammed Bagega, dupẹ lọwọ gomina lorukọ ileeṣẹ ọlọpaa ati ẹṣọ alaabo to ku pẹlu bo ṣe mu ọrọ eto aabo ni ọkunkundun, to si n ṣe iranwọ nigba gbogbo. Bagega fi da gomina loju pe awọn yoo lo irinṣẹ naa bo ti tọ ati bo ṣe yẹ.