Florence Babaṣọla
Ere asapajude lawọn eeyan agbegbe Gbaẹmu, niluu Oṣogbo, sa nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti awọn ikọ ọlọpaa Puff Adder atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kọju ija sira wọn nibẹ.
Ile kan ti wọn n kọ lọwọ lagbegbe naa la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ti wọn to ogun ya lọ, wọn si sọ fun awọn oṣiṣẹ ibẹ pe dandan ni ki wọn sanwọ ọmọ onilẹ.
Awada lawọn oṣiṣẹ ti wọn n kọle ọhun pe ọrọ yii, afigba tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa sọ pe wọn ko ni i ṣiṣẹ kankan lai sanwo ti wọn n beere lọwọ wọn.
Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe lasiko ti idunaadura n lọ lọwọ ni mọto awọn ọlọpaa naa kọja, awọn agbofinro mẹta pere ni wọn si wa nibẹ.
Nigba ti wọn gbọ nnkan to ṣẹlẹ, wọn paṣẹ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kuro nibẹ, ṣugbọn bii igba ti awọn ọlọpaa naa ṣẹso iya ni, ṣe lawọn eeyan yii kọ lu wọn, ti wọn si ṣe wọn leṣe.
Bayii lawọn ọlọpaa yii ranṣẹ si agọ wọn, awọn ẹgbẹ wọn ba wa sibẹ lati ran wọn lọwọ pẹlu ibọn to n dun lakọlakọ nibẹ, ọwọ si tẹ meji lara wọn.
A gbọ pe ṣe lawọn ti wọn ni ile ati ṣọọbu lagbegbe naa n sa kijokijo kiri, ti wọn si n bẹru ki aṣita ibọn ma lọọ ba awọn.
Koda, alubami ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii lu ẹnikan to n ṣiṣẹ POS lagbegbe naa nigba ti wọn fura si i pe o n fi foonu rẹ ka nnkan to n lọ silẹ, bẹẹ ni wọn si tun ko owo ti wọn ba ninu ṣọọbu rẹ.
Gbogbo igbiyanju akọroyin wa lati gbọ alaye nipa iṣẹlẹ naa latọdọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, lo ja si pabo, nitori ko gbe ẹrọ ibanisọrọ rẹ.