A ti n mura lati yanju wahala awọn agbẹ ati Fulani ni Kwara- NSCDC

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹsọ alaabo, aabo ara ẹni laabo ilu, (NSCDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti sọ pe awọn ti n gbero lati da si i, ki awọn si wa ojutuu si aawọ to n ṣokunfa ikọlura laarin awọn agbẹ ati Fulani darandaran nipinlẹ Kwara.

Ọga agba ajọ ọhun, Ọgbẹni Iskil Ayinla, lo sọ ọ di mimọ niluu Ilọrin . O ni ajọ sifu difẹnṣi, ẹka ipinlẹ Kwara, ti n gbinyanju lati da si ọrọ awọn agbẹ ati Fulani darandaran ti wọn n ṣe akọlu si ara wọn lemọlemọ. O ni awọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ kan ninu ajọ naa lati maa wa ojutuu si awọn nnkan to n ṣokunfa ija laarin igun mejeeji ọhun.

O tẹsiwaju pe, lati bii oṣu mẹta sẹyin lawọn ti n wa gbogbo ọna lati da si akọlu awọn adaranjẹ sawọn agbẹ, ṣugbọn ọwọ awọn di tori pe awọn dojukọ iṣoro awọn iwa ọdaran miiran.

Ajọ ẹsọ alaabo naa ti wa jẹẹjẹ lati maa tẹsiwaju ninu gbigbogun ti iṣoro eto aabo, paapaa ju lọ eyi to ni i ṣe pẹlu ikọlu awọn agbẹ ati Fulani darandaran nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply