Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ajinigbe to ji Ọba Benjamin Ọshọ ti Eda-Ile, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti ti yọnda kabiyesi naa, lẹyin ọjọ mẹta to lo lọdọ wọn.
Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ni kabiyesi gba iyọnda pẹlu iranlọwọ Amọtẹkun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in. A gbọ pe igbo aginju kan to wa nipinlẹ Kogi ni wọn ti ri Ọba Eda-Ile to fẹsẹ rin jade sọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn yooku ti wọn n wa a kiri.
Boya wọn waa sanwo tabi wọn o sanwo ki wọn too fi ọba naa silẹ, ọga Amọtẹkun l’Ekiti, Brigedia Joe Kọmọlafẹ, sọ pe oun ko mọ nipa iyẹn. O ni bi awọn Amọtẹkun to ṣaaju nipa wiwa ọba naa ṣe n yinbọn lakọlakọ pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ lo jẹ kawọn ajinigbe yii tete fi kabiyesi silẹ pe ko maa lọ.
Ṣugbọn ọkan ninu ẹbi ọba naa to ba wa sọrọ to si ni ka ma daruko oun, sọ pe awọn sanwo ki wọn too fi ọba silẹ, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii ko sọ pato iye ti wọn san.
Ọjọ Ẹti to kọja ni awọn ajinigbe gbe Ọba Benjamin wọgbo lọ, ti wọn si beere fun miliọnu lọna ogun naira ki wọn too le fi i silẹ.