Awọn ajinigbe n beere fun ọgbọn miliọnu lori Lukman ti wọn pa iyawo ẹ toyun-toyun ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji Lukman Ibrahim gbe, ti wọn tun yinbọn pa iyawo rẹ Hawau toyun-toyun, ni Opopona Ojoku, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, ti n beere fun ọgbọn miliọnu naira, owo itusilẹ, sugbọn ileesẹ ọlọpaa ni awọn mọlẹbi o gbọdọ san owo kankan.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ to kọja, ni awọn agbebọn ji Lukman gbe, ti wọn tun yinbọn pa iyawo rẹ Hawau, toyun-toyun, eyi to sokunfa bi awọn araalu kan ṣe ṣewọde lọ si Aafin Ọlọfa, Mufutau Gbadamosi Esuwọye Keji, ti wọn n beere fun itusilẹ Lukman lati ọwọ awọn ajinigbe.

Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, ni awọn ajinigbe ọhun pe awọn mọlẹbi rẹ, ti wọn si n beere fun ọgbọn miliọnu naira owo itusilẹ. Awọn mọlẹbi ni awọn ti gbinyanju lati ri miliọnu meji naira sa jọ, ati pe agbara awọn o ka ọgbọn miliọnu ti wọn n beere fun, sugbọn awọn ajinigbe kọ jalẹ, wọn ni owo awọn ko gbọdọ din.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti sọ fun awọn mọlẹbi pe wọn ko gbọdọ san owo itusilẹ kankan fun awọn ajinigbe ọhun, toripe awọn ti n sa ipa awọn lati ri i pe, awọn doola ẹmi Lukman, ti yoo si wale layọ ati ni alaafia.

Kọmisanna ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Mohammed Lawal Bagega, ti fi da awọn mọlẹbi ọkunrin naa loju pe awọn ọlọpaa ti wa ni gbogbo agbegbe naa, wọn yoo si wa awọn ajinigbe naa lawari.

 

Leave a Reply