Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori wọn pe ara wọn ni ọlọpaa lai jẹ pe agbofinro ni wọn loootọ, awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ko awọn ọkunrin meji yii, Tajudeen Bankọle ati Fawọyi Rotimi, satimọle, bẹẹ naa ni wọn si ju Oduọla Abiọla toun naa n wọṣọ sifu difẹnsi kiri lai ki i ṣe ara awọn oṣiṣẹ ajọ naa si gbaga.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, lọwọ ba awọn meji to pe ara wọn lọlọpa, Ibogun, nijọba ibilẹ Ifọ, ni wọn ti mu wọn lẹyin tawọn mejeeji lọọ halẹ mọ ọkunrin olotẹẹli kan, Ibikunle Idowu, pe bi ko ba fawọn lowo tawọn n beere lọwọ rẹ, awọn yoo gbe e wọ mọto tawọn gbe wa, o pari fun un niyẹn.
Ọkunrin olotẹẹli naa ko fẹẹ fun wọn lowo kankan, wọn ko si yee dunkooko mọ ọn pe awọn yoo fagidi gbe e lọ, niyẹn ba pe DPO teṣan ọlọpaa Ibogun, CSP Samuel Ọladele, lawọn ọlọpaa ba de otẹẹli naa, wọn si ba awọn ayederu ọlọpaa naa nibẹ, ni wọn ba ko wọn.
Nigba tawọn ọlọpaa fọrọ wa wọn lẹnu wo, ọkan ninu wọn ṣalaye pe ọlọpaa loun tẹlẹ ki wọn too le oun danu nitori aṣemaṣe toun ṣe. Ẹni keji sọ pe oun maa n ta ọlọpaa lolobo lori iṣelẹ ni.
Wọn ṣalaye siwaju pe awọn n kọja lọ lagbegbe otẹẹli naa lawọn ri i pe epo ti tan ninu ọkọ awọn, ko si sowo tawọn yoo fi repo lawọn ṣe fẹẹ dọgbọn gbowo lọwọ olotẹẹli yii, to fi waa di wahala sawọn lọrun bayii.
Iwe aṣẹ iyẹlewo meji to jẹ tọlọpaa ni wọn ba lọwọ awọn ayederu ọlọpaa meji yii.
Ni ti ayederu Sifu Difẹnsi, Oduọla Abiọla, ẹni ọdun mokanlelogbon, foonu kan ti wọn ji lawọn ọlọpaa tọpinpin ẹ de ọdọ ọkunrin yii, n’Ibara, l’Abẹokuta.
Nigba ti wọn mu un, aṣọ iṣẹ awọn Sifu lo wọ, bẹ́ẹ̀ ki i ṣe ara wọn. Bi ẹsun tiẹ ṣe di meji nìyẹn.
Oduọla ṣalaye ibi to ti ri yunifọọmu aawọn sifu, o loun ji i lọdọ oṣiṣẹ ajọ naa kan ni.
Gbogbo awọn tọwọ ba yii ni wọn ti wa nibi ti wọn ti n sọ tẹnu wọn fọlọpaa, ti wọn yoo si gba ibẹ dele-ẹjọ.