Ibrahim Alagunmu Ilọrin,
Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ọrọ di bo o lọ ya fun mi, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan kọju ija sira wọn, ni agbegbe Ita-Kudimọ si Opopona iIe ọba (Emir’s road), ti wọn si ṣeku pa ọkan lara wọn, Bashir, ti inagijẹ rẹ n jẹ Figo.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa ni awọn olugbe agbegbe ọhun bẹrẹ si i sa kijo-kijo, ti onikaluku n sa asala fun ẹmi rẹ. Ẹni ori yọ o dile, gbogbo awọn ọlọkada ati onimọto ni wọn n lọri pada, gbogbo awọn araadugbo ni wọn n tilẹkun mọri, ti opopona si da paroparo lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n ṣakọlu sira wọn pẹlu ohun ija oloro loriṣiiriṣii.
Lakooko ti wọn ṣe akọlu yii, ni wọn ṣa Bashir ladaa titi ẹmi fi bọ lara ẹ.
Titi ta a fi pari iroyin yii, ko sẹni to ti i le sọ ohun to fa akọlu ti wọn ṣe si ara wọn yii.
Nigba ti a pe Alukoro ọlọpaa Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, lati beere nipa iṣẹlẹ naa, ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ.