Ọwọ tẹ babalawo pẹlu ori oku meji, o ni ọdọ ọrẹ oun loun ti ra a l’Ọṣun

 

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ babalawo kan ti wọn porukọ ẹ ni Godfrey Akpuje, ẹni ọgọta ọdun, ti wọn fẹsun kan pe iṣẹ babalawo tiẹ ko gba ẹyẹ ati ẹran fun etutu, niṣe lọkunrin naa maa lọọ n hu ori awọn oku kaakiri itẹkuu, agbari oku meji si ni wọn ka mọ ọn lọwọ.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa to mu un ṣe ṣalaye, wọn ni lọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, lọkunrin kan ti wọn n pe ni Ejiro Okoro, ẹni ọdun marundinlogoji, wa si teṣan awọn lati waa fẹjọ sun pe aunti oun ti wọn forukọ bo laṣiiri, ẹni ọdun marundinlaaadọrin, tawọn sinku rẹ lọdun meji sẹyin, ṣadeede lawọn ri i pe wọn ti lọọ hu oku rẹ ni itẹkuu Ekpan Ovu, tawọn sin in si nipinlẹ Delta, wọn si ti gbe korofo agbari rẹ lọ, awọn o si mọ ẹni to ṣiṣẹ ibi ọhun.

Kia lawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹ sigboro, wọn bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ amookunsika ẹda to wa nidii aṣakaṣa ọhun.

Atẹjade kan ti Alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Edafe, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, sọ pe lẹyin iwadii ati itọpinpin tawọn ọtẹlẹmuyẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Isiokolo ṣe, wọn ri i pe afurasi ọdaran to ṣiṣẹ buruku ọhun ni Godfrey Akpudje, wọn si ti fi pampẹ ofin gbe e lọgan.

Ni teṣan wọn, wọn lo jẹwọ pe ki i ṣe ori oku kan loun hu, agbari oku ti wọn si ka mọ ọn lọwọ to meji, ṣugbọn o ni gbogbo ẹ naa kọ lo jẹ pe oun maa n lọọ hu u, o loun ra awọn agbari oku kan lọwọ babalawo ọrẹ oun kan to wa nipinlẹ Ọṣun, o si ti pẹ toun ti ra wọn pamọ sile fun lilo, ṣugbọn ọkunrin to ta a foun naa ti ku bayii.

Awọn ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, ati pe akata awọn ni babalawo aramanda ti ko jẹ kawọn oku olokuu sun jẹẹjẹ yii maa wa titi tawọn yoo fi taari ẹ siwaju adajọ, tiwadii ba pari.

Leave a Reply