Lẹyin ti wọn gba miliọnu meji, awọn ajinigbe tu Lukman ti wọn pa’yawo ẹ toyun-toyun ni Kwara silẹ 

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ, alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lawọn ajinigbe to ji Lukman Ibrahim gbe, lẹyin ti wọn pa iyawo rẹ, Hawau, toyun-toyun, tu u silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu meji lọwọ mọlẹbi.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni wọn ji Lukman gbe ni Ojoku, nitosi Ọffa, nijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si tun yinbọn pa iyawo rẹ toyun-toyun. Ọgbọn miliọnu naira ni wọn kọkọ beere fun lọwọ awọn mọlẹbi, ti awọn yẹn si ni miliọnu meji pere lawọn ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara waa sọ fawọn mọlẹbi pe wọn ko gbọdọ sanwo itusilẹ kankan fawọn ajinigbe naa, ati pe awọn o fọwọ si idunaa-dura pẹlu awọn ajinigbe.

Ni bayii, awọn ajinigbe naa ti tu Lukman silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu meji lọwọ mọlẹbi rẹ, to si ti dara pọ mọ wọn niulu Ọffa.

 

 

Leave a Reply