Ileeṣẹ ọlọpaa lẹnikẹni o gbọdọ ṣewọde ‘Oodua Nation’ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ko ni i faaye gba iwọde eyikeyii lori idasilẹ orileede Yoruba tawọn kan n gbero rẹ lati waye nipinlẹ Eko, wọn ni kawọn ti wọn n dabaa iwọde naa tete yaa tun ero wọn pa, ti wọn ko ba fẹẹ kan idin ninu iyọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Oluṣẹgun Odumosu, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lori atẹ ayelujara l’Ọjọbọ, Tọsidee yii.

Odumosu ni awọn ti ri atẹjade kan ti ẹnikan to pera ẹ ni Ọlayọmi Koiki fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹfa, nibi to ti ni awọn ti pari eto lori iwọde nla tawọn fẹẹ fi kadii awọn iwọde ati ipolongo ti wọn n ṣe lori idasilẹ orileede Oodua ti wọn n sọrọ ẹ.

O ni wọn sọ ninu atẹjade naa pe ọjọ kẹta, oṣu keje yii, lawọn fẹẹ ṣewọde ọhun ni Gani Fawẹhinmi Freedom Park, to wa lagbegbe Ọjọta, nipinlẹ Eko.

Odumosu sọ pe awọn fẹẹ kilọ fun ẹnikẹni to le wa nidii iru iwọde bẹẹ lati ma ṣe dan an wo, tori awọn yoo jẹ ki ẹnikẹni tọwọ wọn ba ba fimu kata ofin.

Wọn tun sọ pe olobo kan ti ta awọn pe ọga awọn onimọto kan, n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, fẹẹ waa ṣe akọlu sawọn ti wọn fẹẹ ṣewọde l’Ekoo yii. Wọn lawọn gbọ pe wọn fẹẹ waa gbẹsan bi awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho kan ṣe ṣeku pa ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn lasiko tiru iwọde yii waye n’Ibadan lọjọsi.
Wọn tun ni ohun tawọn gbọ ni pe bi wọn ṣe fẹẹ ṣewọde naa ni Ọjọta, bẹẹ ni yoo maa waye lawọn agbegbe pataki mi-in l’Ekoo, bii Too-geeti Lẹkki, Ikẹja, Surulere, Ikoyi, Iyana-Ipaja, Ikorodu, Ikọtun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Odumosu lawọn ko ni i faaye gba iru iwọde yii, gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati gbegi dina rẹ, ntori iwadii tawọn ṣe fihan pe niṣe ni wọn maa fi iwọde naa dana ijọgbọn s’Ekoo.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni kawọn araalu maa lọ sẹnu okoowo ati ibi ọrọ-aje wọn wọọrọwọ, ki wọn ma si feti si ọrọ tawọn eeyan n sọ lati ṣeruba wọn, tori ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti gbaradi lati pese aabo to peye lọjọ naa.

 

Leave a Reply