Faith Adebọla
Latari bawọn ṣọja atawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa ṣe lọọ ṣakọlu sile Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho loru mọju Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, awọn Yoruba to wa loke okun ti bẹrẹ iwọde niluu London, wọn lawọn ko fara mọ iṣẹlẹ naa rara.
Iwọde naa ti ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba lẹyin odi (Yoruba in Diaspora) ṣagbatẹru ẹ waye lọjọ Ẹti, Furaidee yii, niwaju ọfiisi aṣoju orileede Naijiria, iyẹn Ẹ mbasi Naijiria to wa ni London, lorileede United Kingdom.
Bawọn oluwọde naa ṣe n kọ ọkan-o-jọkan orin ẹhonu, ti wọn n sọ pe iwa aidaa nijọba apapọ ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ hu, bẹẹ ni wọn gbe oriṣiiriṣii akọle dani.
Lara awọn akọle naa ka pe: “Orileede Yoruba la fẹ bayii,” “A o ni i boju wẹyin lori ọrọ orileede Oodua,” “Orileede Oodua gbọdọ waye,” “Ẹ fi Sunday Igboho lọrun silẹ o,” “Sunday Igboho ko ṣẹjọba o” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọkan lara awọn oluwọde ọhun to ba awọn oniroyin sọrọ lede Gẹẹsi, Ọgbẹni Peter Ọladele, sọ pe idi tawọn fi ṣewọde naa ni lati fi iṣẹ ran aṣoju Naijiria sile lati ẹmbasi wa pe “o ti to gẹẹ. Ẹ wo iwakiwa, iwa ọdaran ati ifẹmiṣofo tawọn janduku agbebọn ti ṣe ti wọn o si jawọ. O ti to gẹẹ, a o ṣe Naijiria mọ, a o fẹ Naijiria mọ. Ẹyin Sunday Igboho la wa, ohun to daa ni Sunday Igboho n ṣe, ki i ṣe ọdaran rara.”
Abilekọ Grace Dada, toun naa ṣewọde sọ pe “Ki nijọba apapọ fẹẹ sọ pe Sunday Igboho ṣe fawọn. Gumi to n sonibaara awọn agbebọn ajinigbe, ijọba o lọọ mu un, wọn o kọ lu u, ki lo de ti wọn o lọọ mu oun yẹn?
Wọn lọọ paayan meji nile ẹni ẹlẹni. A fẹ ki wọn tu awọn ti wọn mu silẹ kiakia. Awa Yoruba ki i ṣe ọdaran, eeyan alaafia ni wa. Gbogbo iwọde t’Igboho n ṣe kaakiri la n wo nibi, ko seyii to la jagidi-jagan lọ.”
Bẹẹ ni wọn tun kọ lẹta kan sijọba apapọ, wọn si ni ki aṣoju Naijiria to wa lẹmbasi ọhun ba awọn tete fi jiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari.