Faith Adebola
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣekilọ pe ko gbọdọ si iwọde kankan, sibẹ awọn ọmọ Yoruba kan jade, wọn si kora wọn jọ, lati fi ẹhonu han. Ariwo ti tọmọde tagba wọn n pa ni pe awọn ko ṣe Naijiria mọ, Yoruba Nation lawọn fẹ.
Bi awọn eeyan naa ṣe n pariwo Yoruba Nation ni wọn n pariwo Sunday Igboho, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu awọn iwa ti ijọba Naijiria hu si ọkunrin ajijagbara yii.
Ko pẹ rara ti awọn agbofinro ri i pe awọn eeyan naa ti n pọ si i, ati pe ohun wọn ti n rinlẹ ti wọn fi bẹrẹ si i tu omi gbigbona jade lati fi tu wọn ka.
Ọkọ nla kan to kun fun omi gbigbona yii ni wọn ti gbe kalẹ lataarọ. Ṣugbọn wọn ti bẹrẹ si i tu u si awọn oluwọde naa lara, ti wọn si n fi mọto le wọn lọ si agbegbe Maryland.