Irọ nla! Ẹnikẹni ko mu emi ni temi o – Sunday Igboho

Oloye Sunday Adeyẹmọ, Sunday Igboho ti sọrọ lori ahesọ kan to n lọ kaakiri bayi pe wọn ti mu ọkunrin ajijagbarar naa ni Gurumaraji, nitosi Ibadan. Ọkunrin naa sọrọ jade ninu fidio kekere kan pe oun naa ti gbọ nipa ahesọ naa, ṣugbọn oun fẹe fi da gbogbo aye leti pe ko si ẹni kankan to mu oun ni toun, oun wa ninu ile oun n’Ibadan.

Igboho ni, “Mo ti gbo nipa rumọosi kan to n lọ pe wọn ti mu mi ni Gurumaraji. Wọn ko mu emi o, emi wa ni Ibadan ninu ile mi. Ẹ ṣeun mo dupẹ, gbogbo ẹyin Ololufẹ mi, aye ko ni mu gbogbo wa o!”

Lojiji ni ariwo naa jade ni ọsan ana pe wọn ti mu Sunday Igboho, ọrọ naa si ko gbogbo awọn ololufẹ rẹ lọkan soke, nitori o n ya wọn lẹnu bi wọn ti ṣe ri i mu bẹẹ, ẹru si ba wọn gidi lori ati ohun ti awọn aja ijoba wọnyi le fi oju rẹ ri lọdọ wọn. Ṣugbọn ọrọ naa ti ja si ahesọ lasan bayii, Sunday Igboho ti ni wọn ko mu oun o.

Leave a Reply