Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ẹgbẹ okunkun kan wa ti wọn n pe ni ‘Supreme Vikens Confraternity’. Ẹgbẹ naa lawọn gende mẹta yii torukọ wọn n jẹ Willimas Omoori (Tension), Edet Godswill ati Emmanuel Dimgba n ṣe n’Igbẹsa, nipinlẹ Ogun.
Afi bi wọn ṣe fipa mu ọkunrin kan to n lọ jẹẹjẹ ẹ, iyẹn Celestine Onyebuchi, ti wọn gbe e wọ ile akọku, ti wọn si fi lilu ba aye rẹ jẹ, ti wọn tun fun un ni ẹjẹ mu. Ni wọn ba ni o ti di ọmọ ẹgbẹ awọn niyẹn.
Ọjọ kẹjọ, oṣu keje yii, niṣẹlẹ naa waye bi Celestine ti wọn fipa mu wọ ẹgbẹ ṣe ṣalaye fawọn ọlọpaa.
Ọkunrin naa sọ pe oun ko mọ awọn mẹta yii ri tẹlẹ, niṣe ni wọn ji oun gbe wọle akọku naa lọ, ti wọn lu oun bajẹ, ti wọn si tun fun oun lẹjẹ mu. O ni wọn sọ foun pe oun ti di ọmọ awo niyẹn, oun ti di ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Supreme Vikens Confraternity.ẹ
Onyebuchi ṣalaye pe lẹyin toun jaja bọ lọwọ wọn loun waa sọ fawọn ọlopaa ni teṣan Igbẹsa, ki wọn le gbe igbesẹ to yẹ.
SP Abayọmi Adeniji ni DPO teṣan naa, oun atawọn ikọ rẹ dọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun, wọn si ri wọn mu.
Nigba ti wọn n jẹwọ ẹṣẹ fawọn ọlọpaa, awọn mẹtẹẹta sọ pe ero ko pọ ninu ẹgbẹ awọn ni, awọn si nilo ọmọ ẹgbẹ si i.
Wọn ni bawọn ba fi ojubọrọ parọwa fun Onyebuchi, ko ni i fẹẹ dahun, awọn ko si fẹ ko kọ ohun awọn lo jẹ kawọn kuku fipa ki in mọlẹ, tawọn ṣoro ẹgbẹ fun un, to fi di ọmọ awo.
Iwa ti wọn hu yii lodi sofin ni gbogbo ọna, fun pe wọn tiẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun na, ẹsun kan ni. Wọn tun waa fipa mu ẹlomi-in wọ ọ, ẹsun keji.
Eyi lo jẹ ki CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn ko awọn mẹtẹẹta lọ sẹka ti wọn ti n gbọ ẹsun ẹgbẹ okunkun ṣiṣe.
Ajogun sọ pe aaye ko si fawọn ẹlẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ogun, nitori wọn yoo pada bọ sọwọ ọlọpaa ni. O ni kawọn to ba fẹẹ kọ ẹgbẹ naa silẹ tete wa kọwọ ofin too ba wọn, iyẹn daa fun wọn ju ki wọn bọ sọwọ lọ.