Wọn ti dajọ iku fun Morẹnikeji to fun iyawo ọga ẹ lọrun pa l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bo ṣe tan iyaale ile kan, Rachael Oyewumi Ayanwale, jade kuro nibi iṣẹ, to si lọọ fun un lọrun pa sinu igbo, ile-ẹjọ ti dajọ iku fun ọkunrin ẹni ogoji ọdun kan, Morẹnikeji Adeyẹmi lọjọ Ẹti, Furaidee, ta a lo tan yii.

Ṣaaju l’Onidaajọ Adenikẹ Adeẹyọ ti i ṣe adajọ ile-ẹjọ giga to wa lọna ilu Aawẹ, niluu Ọyọ, ti sọ ọkunrin naa sẹwọn ọdun mẹrinla lori ẹsun ole ti wọn fi kan an pẹlu bo ṣe ji ọkọ ayọkẹlẹ Abilekọ Rachael ti i ṣe iyawo ọga ẹ nigba kan.

Ninu ẹsun meji ti wọn fi kan an niwaju adajọ, ẹsun ipaniyan ati ẹsun ole, lọkunrin ọdaran naa ti sọ pe oun ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun naa bo tilẹ jẹ pe ṣaaju lo ti jẹwọ fawọn ọlọpaa atawọn oniroyin ninu ifọrọwerọ ọtọọtọ ti wọn ṣe fun un lọdun 2019, pe oun loun pa iyawo ọga oun atijọ naa.

Ni nnkan bii aago meji ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun 2019, l’Abilekọ Ayanwale dagbere nibi to ti n ṣiṣẹ, iyẹn nile-ẹkọ nipa ilẹ wíwọ̀n (Federal School of Surveying)

to wa niluu Ọyọ, ṣugbọn to jẹ pe alọ ẹ nikan ni wọn ri, abọ tun darinako, o doju ala, o tun di ba a ba a pade niwaju Oludumare lọjọ idajọ.

Lọsan-an ọjọ kẹrin, iyẹn Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun 2019, ni wọn ri oku ẹ ninu igbo, labẹ igi ọparun labule kan ti wọn n pe ni Aba Oniyere, lọna Aawẹ siluu Iwo.

Gẹgẹ bii alaye to ṣe fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, lọdun 2019 ọhun, o ni, “Awakọ ni mi. Lati bii ọdun mẹrin sẹyin ni mo ti ba awọn ẹni yii (Ọgbẹni Sunday Ayanwale ati iyawo ẹ, Oloogbe Rachael) ṣiṣẹ gbẹyin. Mo n fi mọto wọn na Worf,  l’Ekoo, si ipinlẹ Kogi. Nitori dídá ti wọn da mi duro lẹnu iṣẹ ni mo ṣe pa iyawo ọga mi.

“Nitori mọto wọn to bajẹ lọwọ mi ni wọn ṣe gba iṣẹ lọwọ mi. Lọjọ ti mọto bajẹ loju ọna, mo pe wọn, wọn ni ki n gbe foonu fun ẹnikan nibẹ yẹn. Mi o tete ri ẹni ti mo maa gbe foonu fun nitori pe inu igbo ni mọto bajẹ si. Ohun to ṣaa jẹ wọn logun ni pe ki n tete tun mọto awọn ṣe, ki n ba awọn gbe e wa. Nigba ti mo fi maa ri mẹkaniiki, o ti to bii ọjọ mẹrin. Igba ti mo de, wọn gbaṣẹ lọwọ mi, iyawo mi si wa ninu oyun nigba yẹn.

“Nigba ti iyawo mi bimọ, mo tun lọọ bẹ wọn pe ki wọn jẹ ki n maa ba wọn ṣiṣẹ lọ pada, wọn ò gba. Ko si si owo ti ma a fi maa tọju iya ati ọmọ. Bi ọmọ yẹn ṣe ku niyẹn. Lati ọdun mẹrin sẹyin yẹn ni ọrọ ti mo n wi yii ti ṣẹlẹ. Latigba naa ni mi o ti jeeyan mọ. Iyẹn ni mo ṣe pinnu lati gbẹsan.

“Mo tan obinrin yẹn (Rachael)  jade nibi to ti n ṣiṣẹ ni. Mo ni mo fẹẹ mu un lọ sibi adua kan. O si ti fi ọrọ ẹ lọ mi tẹlẹ pe ti mo ba ri ibi ti mo le mu oun lọ lati gbadura lati ṣẹgun wahala ti oun n koju ni idile oun, inu oun aa dun. Mo waa sọ fun un nigba naa pe ti mo ba ti ṣetan, ma a pe e.

“Lọjọ yẹn, mo pe e lori foonu pe mo ti ba a ri ibi kan ti wọn ti le fi adua jagun fun un. Ibi iṣẹ lo wa lasiko yẹn. Bi mo ṣe fi mọto gbe e lọ si ọna ilu Aawẹ niyẹn. Nigba ta a kọja Aawẹ, o beere pe ṣe a ko ti i de ibi ti a n lọ ni, mo ni a ko ni i pẹẹ debẹ. Nigba to ya, o ni oun fẹẹ ṣe igbọnsẹ. Mo ni igbọnsẹ n gbọn emi gan-an. O ni ki n kọkọ lọọ ṣe temi.

“Mo wa nitosi ibi to ti ṣe igbọnsẹ tiẹ. Odò kan wa lagbegbe yẹn, odo yẹn lo ti fẹẹ fi omi fọ ọwọ ati ẹsẹ rẹ lẹyin to ṣegbọnsẹ tan. Mo ti kọkọ fẹẹ dariji i, nigba to ya lẹmi eṣu yẹn waa gbe mi wọ. Nibi to ti n fọ ẹsẹ lọwọ ni mo ti lọọ ga a lọrun mọlẹ, ti mo fun un lọrun pa.

“Ibi ti mo pa a si yẹn naa ni mo fi oku ẹ si. Ṣaaju asiko yẹn, mo ti n fi iṣẹ wẹ́lọ̀, ṣugbọn mi o ti i riṣẹ min-in. Lẹyin ti mo pa iyawo ọga mi tan, mo gbe mọto ẹ, mo sa lọ. Mo fẹẹ ta mọto yẹn ki n maa fi owo ẹ jẹun ni. Ibi kan laduugbo UI, n’Ibadan, ni mo ti fẹẹ ta a, ṣugbọn a ko ti i ri ẹni to maa ra a ti awọn ọlọpaa fi mu mi.

“Bi mo ṣe gbe mọto yẹn fun ẹni to maa ba mi ta a ni mo sa lọ s’Ekoo. Sango ti mo wa l’Ekoo lawọn ọlọpaa ti waa mu mi ki wọn too lọọ gbe mọto nibi ti mo gbe e si.”

Njẹ ẹṣẹ wo gan-an niyawo ọga ẹ ṣẹ ẹ ní pató to fi da a loro, ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) yii fesi pe “awọn mejeeji (Sunday Ayanwale ati Rachael aya rẹ) ni wọn maa n fun mi lowo. Owo ti wọn ko fun mi ati lile ti wọn le mi lo fa a ti mo fi ní wọn sinu.”

Ọkunrin ẹni ogoji ọdun yii sọ nigba naa pe ọdun kejilelogun ree ti iya oun ti jade laye, ati pe nitori pe baba oun ko tọju oun lẹyin iku iya oun loun ṣe ya ọmọ buruku.

“Mo yan ẹlẹbẹ lọọ ba a (baba ẹ)  pe ko ṣaanu mi, sibẹ, o kọ, ko tọju mi. Iyẹn ni mo fi lọọ darapọ mọ awọn ọmọ buruku. Iṣẹ awọn to n tẹ iwe jade ni mo kọ, ṣugbọn ko sowo ti mo fẹẹ fi bẹrẹ iṣẹ yẹn, bẹẹ l’Adeyẹmi tun fesi si ibeere awọn oniroyin lọjọ naa lọhun-un.”

Ṣugbọn nigba tọrọ de kootu ni Morẹnikeji pa ohun da, o loun ko mọ nnkan kan nipa iku iyawo ọga oun.

O ni loootọ loun pẹlu oloogbe jọ jade lọjọ to jade laye, ṣugbọn ọkọ obinrin naa, Ọgbẹni Sunday Ayanwale, ṣikẹta awọn ninu irinajo naa nitori ija to wa laarin ọkọ atiyawo naa loun fẹẹ ba wọn pari lọjọ yẹn ti irinajo fi pa awọn pọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu igbẹjọ to ti waye ṣaaju, “nigba ta a de ibi kan bayii ni madaamu sọ pe awọn fẹẹ ṣegbọnsẹ. Ọga naa si tẹle wọn lọ sinu igbo ti wọn ti lọọ ṣegbọnsẹ. Ṣugbọn nigba ti ọga maa jade, awọn nikan ni mo ri. Wọn sì fi oogun kan lu mi. Latigba naa ni mi o ti mọ nnkan ti mo n ṣe mọ.”

Ṣugbọn Onidaajọ Adeẹyọ ko gba awijare ọhún gbọ, o ni ọdaran yii gọ, o ni nigba to ni wọn fi oogun mu oun niye lọ, bawo lo ṣe wa mọto oloogbe ti nọmba rẹ jẹ KJA 67 CY funra rẹ lọ sibi to ti fẹẹ ta a niluu Ibadan ki awọn ọlọpaa too ri i mu.

O ṣalaye pe niwọn igba ti ẹri ti fi hàn pé Morẹnikeji lo tan oloogbe jade kuro nibi iṣẹ ẹ, ti ko si dari wale mọ, to tun jẹ pe ọwọ oun yii kan naa ni wọn ti ba ọkọ ayọkẹlẹ oloogbe pẹlu ẹrọ ibanisọrọ mejeeji, ko tun si ẹri to le fidi ẹ mulẹ ju bẹẹ lọ pe oun gan-an lo payawo ọga ẹ.

Lasiko yii ladajọ beere bi Morẹnikeji ba ni nnkan kan i sọ ki oun too gbe idajọ oun kalẹ, nigba naa lọkunrin apaayan yii l’anu sọrọ, o ni, “Ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi, nitori mi o lẹnikankan. Ko si nnkan ti mo fẹẹ sọ naa ju pe kẹ ẹ ṣiju aanu wo mi lọ.”

Lẹyin naa lagbẹjọro olujẹjọ, Amofin B.A Oyelami rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo onibaara oun ninu idajọ ẹ nitori to ṣi ni baba laye, ati pe ki wọn wo ti iya ti yoo jẹ awọn ọmọ ati iyawo ọkunrin naa ti wọn ba da ẹjọ to le koko fun un.

Ṣugbọn Amofin Kayọde A. Babalọla ta ko o, o ni ẹlẹṣẹ kan ko gbọdọ lọ lai jiya, ati pe gbogbo ọran lo ti ni odiwọn ijiya to wa fun ọkọọkan wọn. Nitori naa, oun rọ ile-ẹjọ lati dajọ naa gẹgẹ bo ba ṣe yẹ ni ibamu pẹlu iwe ofin ilẹ yii.

Ninu idajọ ẹ, Onidaajọ Adeẹyọ sọ pe, ‘Nitori awọn alaye ti mo ti ṣe ṣaaju wọnyi, o (olujẹjọ) jẹbi ẹsun ole, eyi to mu mi sọ ẹ sẹwọn ọdun mẹrinla ti ko ni iṣẹ aṣekara ninu.

‘’Bakan naa, o jẹbi ipaniyan. O wu mi lati ṣiju aanu wo ọ gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ ṣe bẹbẹ, ṣugbọn ko si ijiya mi-in ta a tun le fun ẹni to ba paayan ju idajọ iku lọ. Nitori naa, o jẹbi iku, mo si ṣedajọ iku fun ẹ.”

Leave a Reply