Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Ori lo ko baba agbalagba ẹni aadọrin ọdun kan, Alagba Samson Ogundiya, diẹ lo ku kawọn Fulani darandaran ti wọn n dọdẹ rẹ lati ji i gbe iba fi ri i mu.
Deedee aago mẹta aabọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye nileetura kan ta a forukọ bo laṣiiri niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ.
Gẹgẹ bawọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti ṣe wi, wọn ni adugbo Ayekalẹ ni baba agbalagba to jẹ ọmọ bibi ilu Ṣaki yii n gbe, ṣugbọn lati igba pipẹ sẹyin ni aisan kan ti da a gunlẹ, ko si ti i ju oṣu meloo kan lọ ti ara rẹ ṣẹṣẹ n ya.
Bi ara baba naa ṣe n ya lo bẹrẹ si i tọrọ baara lawọn otẹẹli kaakiri ilu Ṣaki, tori atijẹ atimu, awọn ẹlẹyinju aanu si maa n fun un lowo, owo naa ni wọn ni baba naa fi n dọgbọn sọrọ ara ẹ.
Baara yii ni wọn ni baba naa fẹẹ lọọ tọrọ gẹgẹ bii iṣe rẹ lọjọ iṣẹlẹ yii, ṣugbọn bi ọkada to gun de otẹẹli ni afurasi ọdaran kan ti n tẹle e, gbogbo ibi ti baba naa ba rin si ni wọn ni Abubakar naa n rin si, bẹẹ ni wọn lo n wo fotifoti lati mọ boya awọn eeyan kan n ri oun.
Ṣe Awodi oke ko kuku mọ pe ara ilẹ n wo oun, awọn ti wọn ti mọ baba naa deledele ni wọn fura si irin Fulani to n lugọ kaakiri yii, ni wọn ba lọọ ba a pe ki lo n wa.
Wọn lafurasi ọdaran naa sọ pe ọrẹ oun ni baba arugbo toun n tẹle, o ni oun mọ baba naa daadaa ati pe adugbo kan naa lawọn jọ n gbe.
Ṣugbọn nigba toun ati baba foju rinju, Alagba Ogundiya loun ko mọ ọn ri, oun ko si ni ọrẹ to jẹ Fulani ri, lakara ba tu s’epo.
Lọgan ni wọn ti pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun lori aago, ti wọn si fa a le wọn lọwọ.
Nigba to de ọfiisi awọn Amọtẹkun to wa laduugbo Ajegunlẹ, Abubakar jẹwọ pe loootọ loun ko mọ baba naa ri tẹlẹ, o ni adugbo Abalu ti ko jinna si agbegbe Kọọmi, niluu Ṣaki, ni Gaa awọn wa, ibẹ lo loun ti wa, iṣẹ darandaran loun n ṣe kaakiri inu igbo, ati pe ẹgbọn oun to porukọ ẹ ni Ibrahim to n fi ọkada ṣiṣẹ ṣe loun n pe lori aago.
Wọn lo tun jẹwọ pe oun n pe ẹgbọn oun ọhun lati wa nitosi ni, ko le ba oun gbe baba naa sa lọ, toun ba ti ji i gbe.
Awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti gba ọrọ wọnyi silẹ lẹnu afurasi ọdaran naa, wọn si ti kan sawọn agbofinro lati fa a le wọn lọwọ fun iwadii ati igbesẹ ofin to yẹ.