Wọn ti mu Taye ati Isiaka, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ijanikin  

Faith Adebọla, Eko

 ‘Ọmọ oró’ ni wọn mọ awọn gende meji tẹ ẹ n wo ninu fọto yii si, awọn ọdaju ọmọ ni wọn n pe bẹẹ, tori wọn yawọ ninu fifibọn paayan, ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ni wọn, idi ẹgbẹkẹgbẹ naa lọwọ awọn ọlọpaa si ti ba wọn, ti wọn fi gbe wọn janto.

Taye Isreal lorukọ ẹni kin-in-ni, ekeji rẹ ni si n jẹ Isiaka Afeez. Agbegbe Ọtọ-Awori, ni Ijanikin, lọna Badagry, nipinlẹ Eko, lọwọ awọn agbofinro ti ba awọn mejeeji yii lọjọ Aiku, Sannde yii, aake sagila kan bayii ni wọn ka mọ wọn lọwọ, nibi ti wọn ti n le awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mi-in kiri pe awọn fẹẹ gbẹsan lara wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi sọ f’ALAROYE pe nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ naa lawọn ọlọpaa teṣan Ijanikin gba ipe idagiri, wọn lẹnikan lo ta wọn lolobo pe awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun tun ti bẹrẹ ija wọn o, wọn ti n le ara wọn kiri, wọn si ti ko jinnijinni ba awọn olugbe agbegbe ọhun.

Kia ni wọn lawọn ọlọpaa naa ti kan si awọn ọtẹlẹmuyẹ, bi wọn si ṣe de agbegbe naa ni wọn ṣe kongẹ awọn afurasi meji yii pẹlu aake ti wọn gbe dani, ni wọn ba mu wọn.

Wọn tun dọdẹ awọn ẹlẹgbẹ okunkun mi-in ni ibuba wọn, ṣugbọn awọn yẹn tete fura, boya ẹnikan lo si sọ fun wọn, wọn ni kawọn ọlọpaa to debẹ ni kaluku wọn ti ya danu, ṣugbọn wọn ṣi n wa wọn lọwọ.

Lara awọn nnkan ija ti wọn ba lọwọ awọn afurasi ọdaran tọwọ ba yii ati ni ibuba wọn ni ibọn ibilẹ kan, ada ati ọbẹ oriṣiiriṣii, ọbẹ, oogun abẹnugọngọ, egboogi oloro ati amuku igbo.

Wọn lawọn afurasi naa jẹwọ pe loootọ lawọn n ṣe ẹgbẹ imulẹ, eyi to lodi sofin, ati pe awọn ija nla kan wa laarin awọn ati awọn ẹlẹgbẹ wọn to n ṣe ẹgbẹ imulẹ keji, wọn lawọn lawọn n fi aake ati ibọn wa kiri lati gbẹsan.

Ṣa, wọn ti taari awọn mejeeji yii si ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iṣẹ iwadii to lọọrin, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, si ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun yooku lagbegbe naa lawaari nibikibi ti wọn ba sa pamọ si. O ni latigba degba lawọn yoo maa tọpinpin gbogbo ibuba tawọn afurasi ọdaran ‘ọmọ oro’ ẹlẹgbẹkẹgbẹ yii, ba mori mu si nipinlẹ Eko, lati fọwọ ofin mu wọn.

Leave a Reply