Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ara o rokun, ara o rọ adiyẹ lọwọlọwọ bayii lawọn agbegbe kan niluu Oṣogbo, ohun to si fa a ni bi awọn ọlọkada atawọn ọdọ kan tinu n bi ṣe n sẹfẹhonu han kaakiri latari bi ọlọpaa ṣe yinbọn lu ọkan lara wọn.
Nnkan bii aago marun-un irọlẹ oni niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ loju-ọba Ọba lagbegbe Islahudeen to jade si Ring Road niluu Oṣogbo.
Ilegbee gomina ni Oke-Fia lawọn ọlọkada naa kọkọ wọ lọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti wọn n sọ ibẹ ko jẹ ki wọn raaye wọle, bẹẹ ni wọn fi mọto akọtami di ọna abawọle.
Ibinu yii lo mu ki awọn ọdọ kan darapọ mọ awọn ọlọkada naa, ti wọn si bẹrẹ si i dana sawọn orita nlanla bii Lameco, Oke-Fia ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti awọn araalu si n sa kijokijo kaakiri.
Alaroye gbọ pe ọkunrin ọlọkada naa, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Saheed Ọlabomi gbe ọkunrin kan, Tajudeen Ọlabọsipo, sẹyin lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Tajudeen ṣalaye pe ọna Old Ọba lawọn n lọ nigba ti wọn dede kan sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lọna, o ni ọkunrin dẹrẹba ọkọ akoyọyọ kan lo wa ọkọ rẹ di oju-ọna.
O ni “Awọn ọlọpaa kogberegbe fẹẹ mu dẹrẹba naa, ṣugbọn o yari mọ wọn lọwọ, lẹyin ọpọlọpọ iṣẹju ni wọn to ri i gbe sinu ọkọ wọn.
“Nigba ti wọn fẹẹ ma a gbe e lọ ni ọkan lara awọn ọlọpaa kogberegbe naa yinbọn soke lati fi tu awọn onworan ka, ibọn yii lo ba ọlọkada to gbe mi loju, oju-ẹsẹ lo ṣubu lulẹ.
“Ṣe lawọn ọlọpaa yẹn sa lọ nigba ti wọn ri nnka to ṣẹlẹ, awọn eeyan si gbe ọlọkada ọhun lọ sileewosan UNIOSUN Teaching Hospital”
Alaroye gbọ pe loootọ lọlọkada naa ko ku, ṣugbọn ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun lo wa bayii.
ASP Yẹmisi Ọpalọla to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun sọ pe oun ko ti i ni alaye kikun lori iṣẹlẹ naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.