APC yan awọn oloye ẹgbẹ kaakiri wọọdu ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, waye ni awọn wọọdu ti ko din ni igba din meje jake-jado ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun to wa nipinlẹ ọhun, ti ipade naa si lọ nirọwọ-rọṣẹ.

Nigba ti alaga ẹgbẹ ọhun, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Alaaji Abdullahi Samari, n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin, o ni yiyan awọn adari ẹgbẹ ni wọọdu igba kan din meje nipinlẹ Kwara, ọhun waye nipa fifẹnuko lori awọn ti wọn yan naa jake-jado ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bii eto ti Gomina Abdulrazak ti to kalẹ, ti awọn ọmọ ẹgbẹ si tu jade lọpọ yanturu lati kopa ninu eto ọhun.

Awọn asoju ẹgbẹ APC lati ilu Abuja, asoju ajọ eleto idibo nilẹ yii, (INEC), ni wọn peju sibi ipade ọhun.

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati wọọdu Adewọle ti Gomina Abdulrazak, ti wa, Alanamu, Ajikobi, ni Iwọ Oorun lọrin (West), Ila Oorun Ilọrin (East), Ifẹlodun, ni Guusu Kwara, ati ẹkun Ariwa, fi han pe eto naa lọ nirọwọ-rọṣẹ.

 

Leave a Reply