EFCC ti tun mu Bukọla Saraki o!

Faith Adebọla

Ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ti tun mu olori ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Bukọla Saraki. Ẹsun ole ati ṣiṣe arọndarọnda owo, eyi to tumọ si pe to ba kowo jẹ ni Naijiria, wọn yoo ko o lọ soke okun, yoo waa fi ra awọn nnkan mi-in to le maa ta wa ti wọn ko fi ni in mọ pe owo ti wọn ko jẹ lo n na. Tabi ko da ileeṣẹ silẹ lorukọ awọn kan, ko si jẹ pe oun ni yoo maa mojuto o labẹlẹ, ti yoo si maa gba ere ti wọn ba jẹ nibi iṣe ọhun.

Ni ba a ṣe n sọ yii, gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ yii ti wa ni atimọle awọn EFCC, eyi to si ṣee ṣe ki wọn tun gbe awọn ẹjọ kan ti wọn ti pari nipa rẹ dide yatọ si ẹsun tuntun ti wọn fi kan an yii to ni i ṣe pẹlu ole jija, lilo awọn eeyan lati gbe owo tabi lati da ileeṣẹ silẹ, tabi ṣiṣẹ lorukọ rẹ to si jẹ pe oun lo ni wọn.

Wọn ni ọpọlọpọ ọdun lo fi lo awọn eeyan yii lati gbaṣẹ lọdọ ijọba ipinlẹ Kwara nigba to n ṣẹ gomina, to si jẹ pe apo rẹ naa ni ere to ba jẹ lori iṣẹ yii n pada si.

ALAROYE gbọ pe owo ti wọn ni gomina yii ri ninu arọndarọnda bisinẹẹsi to n ṣe yii pọ niye, wọn ni bii ilọpo miliọnu owo Naijiria ati owo ilẹ okeere ni.

A gbọ pe ileeṣẹ EFCC ti ṣawari ọpọ awọn ileeṣẹ ti Saraki n lo lati ṣe awọn iṣẹ oriṣiiriṣii to n ṣe yii ati bi owo ṣe n wọle, to si n jade laarin wọn.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn mu Saraki niluu Abuja. Ibi igbeyawo ọmọ oloṣelu kan ni wọn ni o lọ ti wọn fi mu un

Leave a Reply