Amọtẹkun yinbọn pa Fulani ajinigbe meji l’Ọyọọ, wọn mu mẹta laaye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ajinigbe to n ko iku ati ipaya ba awọn ara ipinlẹ Ọyọ kagbako lọjọ Ẹti, Furaidee, yii, pẹlu bi meji ninu wọn ṣe fori ko iku oro lasiko ti wọn fija pẹẹta pẹlu ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ.

Labule Elewura, nitosi ilu Iwere-Ile, nipinlẹ yii niṣẹlẹ naa ti waye lasiko ti awọn ajinigbe ọhun n gbero lati pitu ọwọ wọn. Oru la gbọ pe awọn olubi eeyan yii wọ abule naa tibọntibọn, eyi to mu ki awọn araalu sare pe awọn Amọtẹkun lati yara waa doola emi wọn. Kò sí ju iṣẹju marun-un lọ ti awọn agbofinro naa fi kan wọn lara.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bi ikọ ajinigbe ẹlẹni marun-un ọhun ṣe ri awọn Amọtẹkun ni wọn doju ija kọ wọn, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn fun wọn.

Ṣugbọn lakọ ni lawọn afurasi ọdaran wọnyi ba awọn agbofinro naa nitori niṣe lawọn Amọtẹkun fibọn wọyaaja pẹlu wọn, lọgan ni wọn yinbọn pa meji ninu wọn, ti wọn si mu awọn mẹta yooku looyẹ.

Fulani ọlọsin maalu ni wọn pe awọn afurasi ọdaran naa.

Akitiyan wa lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ko seso rere, pẹlu bi akoroyin wa ṣe pe Abilekọ Ayọlọla Adedọja ti i ṣe agbẹnusọ fun ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn ti obinrin naa ko gbe ipe ọhun wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply