Abi iru ki tun leyi: Rachael Oniga ti ku o

Ọkan pataki ninu awọn oṣere tiata nilẹ yii, Oloye Rachael Oniga, ti ku o. Aarọ kutu oni yii ni iku mu gbajumọ oṣere naa lọ, ti ẹnikẹni ko si ti i le sọ hulẹhulẹ ohun to pa a.

Ko pẹ rara ti obinrin naa ṣe ọjọọbi, koda ko ti i ju oṣu meji lọ, nitori ni ọjọ kẹtalelogun oṣu karun-un ni wọn bi i; bẹẹ ni ko ti i pẹ to n ba wọn da si awọn ọrọ to n lọ lori ẹrọ ayelujara, ko si sẹni to ro iku ro o, afi bi ariwo iku rẹ ṣe ja sigboro lojiji.

Ọpọ awọn oṣere nla-nla ti Alaroye ba sọrọ fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe ọrọ iku Rachel Oniga ko ni ani-ani ninu, obinrin oṣere nla naa ti lọ.

Ọdun 1957 ni wọn bi i si agbegbe Ebute-Mẹta ni Eko, bo tilẹ jẹ pe ọmọ ilu Eku ni ipinlẹ Delta ni. Ọdun 1993 lo bẹrẹ ere ṣiṣe lẹyin ti ipinya de laarin oun ati ọkọ rẹ, ere rẹ akọkọ to si kopa ninu ẹ ni Onome, ere ede oyinbo ni. Ṣugbọn ere Yoruba to kọkọ ba wọn ṣe ninu rẹ ni Owo Blow, lati igba naa lo si ti duro sidii ere Yoruba, o si le ni ọgọrun-un ere daadaa to ti kopa.

Ẹkunrẹrẹ iroyin iku gbajumọ oṣere naa n bọ laipẹ. Gbogbo awa ololufẹ Rachael Oniga, a ku ara fẹra ku o.

Leave a Reply