Ẹ fọkan balẹ, a ti pari gbogbo eto, Sunday Igboho o ni i pẹẹ kuro ninu ahamọ – Lọọya Igboho

Dokita Oluṣẹgun Falọla, ọkan ninu awọn agbẹjọro ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Subday Igboho, ti ni ki awọn eeyan fọkan balẹ, o ni awọn ti pari gbogbo iṣẹ to yẹ lori ọrọ Igboho, ibi to si de duro bayii, ko sẹni to le gbe e kuro ni orileede Benin lati pe awọn maa da a pada si Naijiria.

Agbẹjọro Fawọle sọrọ yii fun ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, nigba ti akọroyin wa pe e lori foonu.

O ṣalaye pe mimi kan ko le mi Sunday Igboho, ati pe ni ọjọ Ẹti ti oun n ba wa sọrọ yii ni oun fẹẹ ko iwe rẹ lọ si ọdọ adajọ to n gbọ ẹjọ rẹ.

Falọla ni, ‘‘Awọn iwe Sunday Igboho ni mo fẹẹ ko lọ si ọdọ adajọ to n gbọ ẹjọ naa lati yẹ ẹ wo. Mo ti kọkọ lọ sibẹ laaarọ yii, wọn ni ki n pada wa ni aago mẹrin, mo si gbọdọ ri i pe mo ṣe gbogbo eto naa nitori ile-ẹjọ ko ni i ṣi ni ọjọ Satide. Eyi ni idi ti mi o fi le lọọ ki Jimọh, mo fẹẹ ri i pe mo ṣe ohun gbogbo to yẹ.

‘‘Sunday Igboho ni iwe igbeluu gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede Germany, iwe naa ko si ni i pẹẹ lejọ, eleyii si le fa wahala fun un nitori pe o yẹ ko lọ si orileede naa lati ṣe atunṣe iwe yii. Akiyesi eleyii ni mo fẹẹ pe adajọ naa si pe iwe yii ko gbọdọ lejọ si ajijagbara naa lọwọ. Oun naa si jẹ ẹni to nimọ, to si mọ itumọ iwe yii ati ewu to wa ninu ko lejọ siiyan lọwọ. Eleyii la fẹ ki adajọ yii ṣe agbeyẹwo ki wọn le tete gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ Igboho kiakia. A fẹẹ ri i daju pe wọn tu u silẹ ko too di pe iwe naa lejọ, ko le maa lọ si orileede Germany to n lọ ki wahala naa too ṣẹlẹ.’’

Nigba to n ṣalaye idi ti wọn ṣe fi Sunday si ọgba ẹwọn, o ni ki aabo le wa fun un fun igba diẹ ni, ṣugbọn ko tun gbọdọ pẹ ju nibi to wa naa ti ile-ẹjọ fi gbọdọ da a silẹ nitori pipẹ rẹ nibẹ paapaa lewu.

Falọla ṣalaye fun akọroyin wa lori ibeere ta a bi i pe ṣe ko ro pe awọn adajọ le doju ẹjọ naa ru bi ọwọ ba kan ọwọ. O ni, ‘‘Ko sohun to jọ bẹẹ. Awa bii agbẹjọro mẹsan-an la wa lori ẹjọ naa ti a n duro fun Igboho, oju gbogbo ilu ati orileede lo si wa lara ẹjọ naa. Nitori idi eyi, adajọ kankan ko le ṣe bekebeke lori igbẹjọ yii.

‘‘Kinni kan to da mi loju ni pe ninu oṣu ta a maa mu yii, ko le pẹ rara ti ọrọ naa yoo fi yanju patapata, ti Igboho maa kuro ni atimọle ọgba ẹwọn, ti yoo si gba orileeede Gẹmany to n lọ lọ.’’

Eyi ni Falọla fi pari ọrọ rẹ

 

Leave a Reply