Ijọba Dapọ Abiọdun ti ko biliọnu mẹrinlelọgọta owo ijọba ibilẹ gba ibomi-in lọ o  -Ladi Adebutu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ yii, ondije dupo gomina nipinlẹ Ogun lọdun 2019, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, ṣepade pẹlu awọn alaga, igbakeji alaga atawọn kansilọ to yẹ ki wọn dupo ijọba ibilẹ Ogun laipẹ yii lẹgbẹẹ PDP, ṣugbọn ti wọn kọ lati kopa nitori ẹgbẹ paṣẹ fun wọn lati yera fun idibo naa.  Nibẹ ni Adebutu ti sọ ọ di mimọ pe ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ko nawo ijọba ibilẹ sibi to tọ, o ni wọn ti gbe biliọnu mẹrinlelọgọta (64b) gba ibomi-in lọ.

Gbọngan nla kan ni Park inn, Kutọ, l’Abẹokuta, ni l’Adebutu ti sọrọ yii. O ṣalaye pe fun oṣu mọkanlelogun ti Dapọ Abiọdun ti n ṣe gomina ipinlẹ Ogun, wọn ko nawo ijọba ibilẹ ti ijọba apapọ fun wọn sibi to yẹ, niṣe ni wọn ti gbogbo ilẹkun ileeṣẹ ijọba ibilẹ yii pa, ti ko si sohun kan to ṣafihan ohun ti won fi owo bantabanta yii ṣe.

Adebutu fi kun un pe biliọnu mẹrinlelọgọta (64b) nijọba apapọ ti fun ipinlẹ Ogun latigba ti wọn ti de ori aleefa yii, fun ijọba ibilẹ nikan si ni. O ni kin ni Abiọdun fi ṣe, yatọ si ko sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, o ni eeyan ko le ri iṣẹ idagbasoke kan ti wọn ṣe lawọn ijọba ibilẹ kiri.

Ko ṣai mẹnuba idibo ijọba ibilẹ to kọja yii, ninu eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan ko ti kopa latari bi wọn ṣe ni OGSIEC n gbe sẹyin abala kan to si n yọ awọn kan sẹyin. Adebutu sọ pe owo ijọba ibilẹ ni wọn na bo ṣe wu wọn ninu ibo to pe ni awuruju naa, ti wọn si fi ẹtọ awọn ọmọ PDP to yẹ ko dije du wọn, ti wọn ko si jẹ kawọn eeyan dibo fẹni to wu wọn rara.

Adebutu waa ni kawọn ọmọ ẹgbẹ oun ti wọn ko le dije naa fọkan balẹ, oun yoo bu ororo itura sapo wọn fun owo ti wọn na ti ko pada huna ọhun.

Ṣugbọn Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun, Afọlabi Afuapẹ, koro oju si ohun ti Adebutu sọ yii. Afuapẹ sọ pe ase lasan ti ko lẹsẹ nilẹ ni Adebutu gbe jade nigboro ẹnu.

O ni loorekoore nijọba n ṣepade pẹlu awọn ẹka kọọkan ti owo ijọba ibilẹ tọ si, bẹẹ, ọdun kẹfa ree ti wọn ti ṣepade iru ẹ gbẹyin ninu iṣakoso to kọja, ijọba Abiọdun yii lo ji i dide pada, ti wọn si n pin ẹtọ kaluku fun un bi ofin ṣe la a kalẹ.

O ni awọn tiṣa, awọn oṣiṣe ijọba ibilẹ, awọn oṣiṣẹ-fẹyinti atawọn mi-in n gbowo wọn bo ti tọ si wọn.

Afuapẹ ṣalaye pe laipẹ yii ni ijọba yoo gbe eto iṣuna owo ijọba ibilẹ ogun (20 LG) to wa nipinlẹ Ogun jade ninu awọn iwe iroyin, kawọn araalu le foju wọn ri i bo ṣe n lọ.

O loun ṣetan lati koju Adebutu atawọn ọmọ PDP rẹ, ki wọn jẹ kawọn jọ foju koju ki ọrọ le dun un sọ daadaa, nitori ọrọ to ba da ni loju ki i kọsẹ lete ẹni.

 

Leave a Reply