Faith Adebọla
Niṣe lawọn ololufẹ ere bọọlu, paapaa awọn ololufẹ ilumọ-ọn-ka agbabọọlu agbaye nni, Lionel Messi, ya bo papa iṣere Camp Nou ti i ṣe ojuko fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, ti ọpọ lara awọn eeyan naa bu sẹkun, bi wọn ṣe di jẹsi (jersey) ti Messi maa n wọ mu, wọn n daro bi agbabọọlu naa ṣe fẹẹ fi ikọ Barcelona ti wọn n pe ni Barca, silẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn alakooso Barca sọrọ yii di mimọ loju opo wọn lori ẹrọ ayelujara, wọn si tun fi atẹjade naa ṣọwọ sawọn oniroyin agbaye kan pe Lionel Messi ti n tẹsiwaju kuro lọdọ awọn, wọn ni ‘adehun lori owo ati awọn atunto kan to waye’ lo mu ki ọkunrin olokiki naa pọ soke raja lọtẹ yii.
Ọjọ ki-in-ni, oṣu keje, to kọja yii, ni adehun ti Messi ṣe kẹyin pẹlu Barcelona wa sopin, latigba naa lawọn ikọ agbabọọlu mi-in ti n ṣẹwọ si i pe ko maa bọ lọdọ awọn, bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa kọkọ ṣera-ro lati mọ boya oun ti ẹgbẹ agbabọọlu rẹ maa tun adehun mi-in ṣe tabi bẹẹ kọ.
Lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ti fi ifẹ han lati ra Messi ni ikọ Arsenal, PSG ati Manchester City ti wọn n pe ni Man City.
Ọdun mọkanlelogun gbako ni ọjafara alayo ori papa yii fi wa pẹlu Barcelona, aropọ bọọlu ọtalelẹgbẹta ati mejila (672 goals) lo gba wọnu àwọ̀n laarin asiko naa, o si gba ife ẹyẹ liigi La Liga lẹẹmẹwa fun ẹgbẹ rẹ, ti liigi Champions lẹẹmẹrin, ati ti liigi Copa del Reys lẹẹmeje ọtọọtọ.
Yatọ siyẹn, ẹẹmẹfa ni ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lagbaaye fi ami-ẹyẹ agbabọọlu to poju owo ju lọ, eyi ti wọn n pe ni Ballon d’Or, lede Faranse da a lọla.
Ko ti i daju boya yoo ṣee ṣe fawọn to n ṣẹwọ si Messi pe ko darapọ ma’wọn yoo ri i ṣe, ṣugbọn ọgọọrọ awọn ololufẹẹ bọọlu lo n woye ibi ti Lionel Messi yoo duro si lọtẹ yii.