Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, IGP Usman Alkali Baba, ti yan CP Emienbo Tuesday Assayamo gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa tuntun fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ti yoo bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii, CP Frank Mba, fi lede ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ yii, lo ti kede iyansipo naa niluu Abuja, ati awọn kọmisanna mejila mi-in lawọn ipinlẹ mejila bii: Niger, CP Monday Bala Kuryas; Nasarawa, CP Soyemi Musbau Adesina; Taraba, CP Abimbola Shokoya; Benue, CP Akingbola Olatunji; FCT, CP Babaji Sunday; Kogo, CP Arungwa Nwazue Udo; Kaduna, CP Abdullahi Mudashiru; Jigawa, CP Aliyu Sale Tafida; Enugu, CP Abubakar Lawal; Cross River, CP Alhassan Aminu; Bayelsa, CP Echeng Eworo Echeng ati ipinlẹ Kebbi, CP Musa Baba.
Agbẹnusọ ọhun sọ pe awọn mu iṣipopada ba awọn ọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa naa lati mu ki eto aabo duro ire, ti wọn yoo si maa gbogun ti iwa ibajẹ ati iwa ọdaran lorile-ede yii.