Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkan pataki ninu awọn oloṣelu ipinlẹ Ogun, to tun ti figba kan ṣe sẹnetọ nilẹ wa, Buruji Kasamu,
Oni ni ọkunrin oloṣelu naa ku si ọsibibitu ti wọn ti n ṣe itọju arun ọkan to wa niluu Eko (First Cardiology Consultants.)
O to ọjọ mẹta ti wọn ni ọkunrin naa ti ni arun Korona, eyi ti wọn lo ti pada ṣẹgun rẹ, ṣugbọn arun naa ti ṣakoba fun awọn ẹya kan ni agọ ara rẹ, eyi to fi pada mu ẹmi rẹ lọ.