O ti dofin! Ọdun mẹta ni darandaran to ba fi maaluu jẹko l’Ọṣun yoo lo lẹwọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti buwọ lu aba ti yoo maa ṣakoso fifi ẹran jẹko ati idasilẹ ibudo ti wọn yoo ti maa sin oniruuru nnkan ọsin, o si ti di ofin bayii

Bakan naa ni wọn buwọ lu ofin ti yoo dẹkun fifiya-jẹni lọna aitọ (Violence Against Persons (Prohibition) Bill 2021).

Gẹgẹ bi Olori ile ọhun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ṣe sọ, ofin naa yoo pinwọ bi awọn darandaran ṣe maa n ba oko oloko jẹ, ti wọn yoo si ba nnkan ọgbin jẹ.

Owoeye fi kun un pe ofin tuntun ọhun yoo fopin si ipaniyan, ifipabanilopọ, yoo daabo bo agbegbe lọwọ wahala ti fifi ẹran jẹko nita gbangba maa n da silẹ.

O ni ti ofin naa ba ti bẹrẹ iṣẹ, ko si ẹnikẹni tabi agbarijọpọ ẹgbẹ to le maa sin ẹranko, da maaluu kaakiri, tabi fi ẹran jẹko kaakiri ipinlẹ Ọṣun yatọ si ibi tijọba ba fọwọ si.

O ni ẹnikẹni to ba ṣe lodi si ofin naa yoo foju wina ofin, ijiya rẹ si ni ẹwọn ọdun mẹta lai si aaye faini rara, bẹẹ nijọba yoo si lagbara lati gbẹsẹ le gbogbo awọn ẹran-ọsin rẹ.

O ni ko saaye fun awọn ọmọde lati da maaluu kaakiri mọ lai ṣe pe awọn agbalagba wa pẹlu wọn. Ibikibi ti iru ẹ ba ti ṣẹlẹ, obi tabi alagbatọ ọmọde bẹẹ yoo san faini ẹgbẹrun lọna ọọdunrun-un naira.

Abẹnugan ṣalaye pe ọmọ orileede yii tijọba ba fun ni aṣẹ ati agbara lati ṣiṣẹ labẹ ofin yii nikan laaye yoo gba nipinlẹ Ọṣun, ijọba yoo si bẹrẹ si i fun awọn eeyan ọhun ni lansẹnsi lati sin ẹran-ọsin nibi to lẹtọọ.

Darandaran tabi ẹlẹran-ọsin to ba ṣekọlu si agbẹ tabi awọn araalu yoo fẹwọn jura, ko si ni i lo kere ju ọdun kan lọ lẹwọn lai faaye faini silẹ.

Bakan naa lo ni aarin aago meje aarọ si mẹfa irọlẹ ni awọn ẹran-ọsin le rin latibikan sibomi-in l’Ọṣun.

 

 

Leave a Reply