Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi ẹbiti ko ba pa eku, o yẹ ko fi ẹyin fẹlẹyin. Bijọba Aarẹ Muhammadu Buhari yii ko ba ni i yee fiya jẹ Yoruba, o di dandan ki wọn gba iran naa laaye lati ni ilẹ Olominira tiẹ, tabi ki ijọba ẹlẹkun-jẹkun tawọn gomina ilẹ Yoruba n beere fun waye.
Eyi lohun ti Aarẹ-Ọna- Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, sọ nibi eto kan ti wọn ṣe fawọn aṣiwaju APC, l’Oṣogbo l’Ọjọbọ to kọja yii.
Aarẹ tẹsiwaju pe iran Yoruba ko le maa jiya lọ bayii labẹ akoso Buhari. O ni iran yii ko le maa gbe ninu oṣi ati ipọnju nilẹ ibi ti wọn ti bi wọn. Ko sohun meji ti yoo si ṣẹlẹ ju pe ki Buhari fi ọwọ mu ọkan ninu ki Yoruba da duro laaye tiẹ, tabi ko si jẹ ijọba ẹlẹkun-jẹkun la oo fi yanju ẹ.
“Mo fara mọ ohun ti Akintoye n wi, nitori bi ẹ ba wo bi wọn ṣe n dari Naijiria yii, eeyan yoo fẹ kijọba ṣe atunto orilẹ-ede yii ni, pe kijọba di ẹlẹkun-jẹkun tabi ki kaluku da duro lominiria tiẹ gẹgẹ bii ẹya. A o le maa jiya lọ bayii, a o le maa da bii ajoji nilẹ baba wa” Bẹẹ ni Aarẹ wi.
Iba Gani Adams fi kun alaye naa pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to wa loke okun yoo darapọ mọ iwọde ti Ọjọgbọn Banji Akintoye yoo ṣiwaju lọ sọdọ awọn Ajọ Agbaye (United Nations), eyi ti yoo waye loṣu kẹsan-an, ọdun yii, nibi ti wọn yoo ti beere fun ominira ilẹ Yoruba.
Nigba to n gboriyin fawọn gomina ẹkun Guusu Naijiria ti wọn dide lati beere fun ijọba ẹlẹkun-jẹkun, Adams sọ pe oun fara mọ ohun ti wọn n beere yii.
O ni ẹgbẹ OPC gẹgẹ bii eyi to n ja fun ominira yoo maa tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ. Awọn naa n beere fun ominira Yoruba, tabi ijọba ẹlẹkun-jẹkun, ọkan ni Buhari fọwọ gbọdọ fọwọ mu ninu mejeeji.