Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kọmisanna ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa si ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Amienbo Tuesday Assayamo, ti ṣekilọ fun gbogbo awọn ajinigbe ati ọmọ ẹgbẹ okunkun lati tete ko aasa wọn kuro ni ipinlẹ naa bayii, o ni ki wọn gba ilu mi-in lọ, tori pe ni akoko ti oun de yii, ipinlẹ Kwara, yoo gbona mọ wọn.
Nigba ti kọmisanna ọhun n ba awọn oniroyin sọrọ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, o ni oun ti gbọ iroyin nipa ipenija aisi aabo bii ijinigbe, ọmọ ẹgbẹ okunkun to n para wọn ati awọn to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara to n ba ipinlẹ Kwara finra, ti gbogbo eto si ti to lati ri i pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia gbogbo eeyan ni tibu-tooro ipinlẹ naa. O tẹsiwaju pe oun ti gbe awọn igbimọ kan kalẹ ti yoo maa ṣe iwadii lori iwa ijinigbe, lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ati ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo si ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba alaye, lẹgbẹ-lẹgbẹ ati lajọ-lajọ, ki aabo to gbopọn le wa nipinlẹ Kwara.
O fi kun un pe, oun ko ri ohun ti yoo fa a ti awọn olugbe Kwara yoo ṣe maa paya tabi bẹru labẹ akoso toun, ki gbogbo awọn araalu maa sun, ki wọn maa han-an-run, ti wọn ba si sun ki wọn diju mejeeji tori pe ko sewu loko, afi giiri aparo.
Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni oun rọ gbogbo lọba lọba, awọn olori ẹlẹṣin, awọn adari awujọ, awọn ẹgbẹ akẹkọọ ati gbogbo ẹsọ alaabo to ku nipinlẹ naa lati fọwọsowọpọ ki erongba ileeṣẹ ọlọpaa le wa si imuṣẹ, tawọn olugbe ipinlẹ naa yoo si maa sun oorun asun han-an-run.