‘Wọn de mi lọwọ lẹsẹ fun ọjọ meji gbako ninu ojo, mi o gbadura iru iriri bẹẹ f’ọtaa mi’

Faith Adebọla

“Wọn foju mi ri mabo nigba ti mo wa lakata wọn, wọn ṣe mi yankanyanyan gidi ni, wọn foju mi gbolẹ, wọn fi mi wọlẹ tuuru ni pẹlu. Mi o gbadura ki ohun ti oju mi ri ṣẹlẹ si ọta ti mo koriira ju lọ paapaa. Haa, mo fi oju mi ri iku bayii, diẹ lo ku ki ẹmi mi bọ.”

Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Niger, Alaaji Mohammed Sani, lo n ṣalaye itu tawọn ajinigbe ti wọn ji i gbe lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, pa fun un ninu igbo ti wọn ji i gbe lọ. O ni ọrọ naa buru gidi tori iya toun o jẹ ri latigba toun ti daye ni wọn fi jẹ oun.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, lori iṣẹlẹ ọhun lẹyin ti ori ko o yọ, tawọn ajinigbe naa yọnda rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, Alaaji Sani ni iriri naa ko bara de rara, titi di asiko yii ni ẹru ṣi n ba oun.

Ninu alaye rẹ, o ni ṣe lawọn agbebọn naa ṣadeede fọ ilẹkun ile oun lọjọ Iṣẹgun ti wọn ji oun gbe. ‘Gbogbo ilẹkun ni wọn fọ, wọn si ki mi mọlẹ, wọn gbe mi lọ sinu igbo kijikiji ti mi o de ri, ti mi o tiẹ le sọ pe ibi bayii ni mo wa. Ibẹ ni wọn ti da mi dubulẹ, wọn de mi lọwọ lẹsẹ bii ọdaran, ori dide ọhun si ni mo wa fun wakati mẹrinlelogun gbako, oorun n pa mi, ojo n pa mi nibẹ.

Pẹlu bi ojo ṣe n pa mi to, wọn o fun mi lounjẹ, ko si somi, wọn da mi lagara patapata. Ṣugbọn nigba to ya, ti wọn ri i pe mi o ṣe bii ẹni pe nnkan ti wọn n ṣe fun mi dun mi, mo gba kamu ni temi, ni aanu mi bẹrẹ si i ṣe wọn, ni wọn ṣẹṣẹ waa fun mi ni ounjẹ ati omi, wọn tu okun ti wọn fi so mi lọwọ, ṣugbọn gbangba ita ni wọn fi mi si, ori mi ni gbogbo ojo nla to rọ lasiko naa da le, boya eyi lo waa jẹ ki wọn fun mi lara awọn tapolin ti wọn fi n bora, wọn ṣaa waa da ọkan bo mi lori ninu ojo naa.”

Ọkunrin naa ni ọna iyanu ni wọn gba tu oun silẹ.  “Ko sẹni to sanwo itusilẹ, ki i ṣe pe awọn agbofinro da mi nide, boya aanu mi naa lo ṣe wọn ni o, mi o le sọ, iyanu nla ni Ọlọrun gbe ọrọ mi gba, Ọlọrun lo fọwọ tọ ọkan wọn ti wọn fi tu mi silẹ pe ki n lọọ ba iyawo atawọn ọmọ mi nile.’’

Sani tun sọ pe bi wọn ṣe ji oun gbe ki i ṣe ọrọ ṣereṣere rara, wọn diidi waa ji oun gbe ni, miliọnu lọna igba naira lo ni wọn fọkan si lati gba lọwọ oun, ṣugbọn o dupẹ pe wọn o gbowo nigbẹyin, ori si tun ko oun yọ, ko sohunkohun to ṣe oun.”

Leave a Reply