Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Pẹlu bi ajakalẹ arun Koronafairọọsi ṣe n ṣoro bii agbọn kaakiri, o ti di eeyan mẹrinlelaaadọrin to lugbadi arun naa nipinlẹ Ọṣun, eeyan meje lẹmii wọn si ti bọ sinu ẹ laarin ọsẹ meji pere.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fọrọ iroyin ati ilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita lo ti pariwo fawọn araalu lati ma ṣe fi ẹmi wọn ta tẹtẹ nipa fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ itankalẹ arun yii.
O ni wọn gbọdọ mu wiwọ ibomu lọkun-un-kundun bayii, ki onikaluku si maa sa fun ipejọpọ ẹlẹni-pupọ, ki wọn si maa fọ ọwọ wọn pẹlu ọṣẹ nigba gbogbo, ki wọn si ma gbagbe lati lo sanitaisa.
Ẹgbẹmọde sọ pe bi awọn araalu ko ṣe ka ọrọ arun ọhun si mọ laarin ipinlẹ Ọṣun naa ni arun Korona n ṣiṣẹ buruku kaakiri, to si n buru si i lojoojumọ.
O gba awọn araalu niyanju lati tete lọ fun ayẹwo arun Korona ni kete ti wọn ba ti kẹẹfin pe aisan n ṣe awọn, dipo ki wọn maa wo ara wọn niran ninu ile.
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ti ṣe ojuṣe tirẹ, o si ku si onikaluku lọwọ lati mu ọrọ aabo ẹmi wọn lọkun-un-kundun.