Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ojiji to pa eeyan meje ninu idile kan ṣoṣo lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, mọjumọ ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii lagbegbe Oke-Suna, niluu Apomu, nipinlẹ Ọṣun.
ALAROYE gbọ pe nigba tawọn araadugbo ko gburoo ki ẹnikankan jade ninu ile naa laaarọ ọjọ Iṣẹgun, ni wọn lọọ kanlẹkun, nigba ti wọn si yọju wonu ile ni wọn ri i pe gbogbo wọn ko mira.
Bayii ni wọn jalẹkun wọle, ti wọn si gbe awọn mejeeje lọ sileewosan kan ninu ilu naa, ṣugbọn lẹyin tawọn dokita ṣayẹwo wọn ni wọn sọ pe awọn mejeeje ti ku.
Ko sẹnikankan to mọ pato ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan yii, ṣugbọn ẹnikan to n gbe agbegbe naa, to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oogun apakokoro lawọn mọlẹbi naa lo sayiika ile ki wọn too sun.
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe iwadii ti bẹrẹ lati le mọ ohun to pa wọn.