Jọkẹ Amọri
Iyalẹnu lo ṣi n jẹ fun gbogbo awọn ti wọn gbọ pe awọn agbebọn ya wọn ileeṣẹ ologun, (Nigerian Defence Academy), to wa niluu Kaduna, ti wọn si ṣakọlu si wọn, nibi ti wọn ti pa ṣọja meji, ti wọn si ji ẹni kan gbe sa lọ laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe aṣọ ologun ni awọn eeyan naa wọ, ti wọn si dibọn bii pe ṣọja ni wọn, eyi lo fun wọn ni anfaani lati kọja lọdọ awọn ẹṣọ to yẹ ki wọn yẹ wọn wo.
Bi wọn ṣe kuro nibẹ ileegbee awọn ọmọ ogun ni wọn kọri si, bi wọn si ti de itosi ibẹ ni wọn da ibọn bolẹ, ti wọn bẹrẹ si i yin in lakọ lakọ. Lasiko yii ni wọn yinbọ pa ọga ṣọja meji, ti wọn si tun ji ẹni kan ti wọn pe ni mejọ lẹnu iṣẹ ologun gbe lọ.
Ariwo ibọn yii lo ta awọn ikọ ayaraṣaṣa awọn ṣọja lolobo ti wọn fi sare bọ sita. Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, awọn agbebọn naa ti sa lọ pẹlu ọkan ninu awọn ṣọja ti wọn ji, awọn ẹṣọ alaabo ayaraṣaṣa awọn ṣọja yii ko ri i gba pada.
A gbọ pe ikọ awọn ologun naa ti bẹrẹ si i wa gbogbo inu igbo, bẹẹ ni wọn gbe baalu to maa n ṣawari awọn inu igbo ati ibi kọlọfin gbogbo jade lati le ṣawari awọn to ṣiṣẹ ibi naa.
Niṣe lẹru bẹrẹ si i ba gbogbo awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ohun ti wọn si n sọ ni pe bi awọn agbebọn ba le wọ ileewe awọn ṣọja lọ, nibo lo ku ti aabo tun waa wa lorileede yii.