Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari iṣẹ abẹ ti agba oṣere nni, Ẹbun Oloyede tawọn eeyan mọ si Ọlaiya Igwe, ṣe laipẹ yii, ti ara rẹ si ti n ya daadaa, Aarẹ ẹgbẹ TAMPAN atawọn agba ẹgbẹ kan ṣabẹwo si i niluu Eko lọjọ Aiku, Sannde yii, nile rẹ to wa ni Ajao Estate.
Ọtunba Bọlaji Amusan, iyẹn Mista Latin to jẹ Aarẹ TAMPAN lo lewaju awọn oṣere yooku bii Yọmi King (Ọpẹbẹ), Ọgbẹni Owolabi Ajasa to jẹ gomina ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun pẹlu awọn alakooso ẹgbẹ ti wọn jọ lọ.
Ṣe ni nnkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin ni iroyin kan gbode pe Ọlaiya Igwe ti ku lẹyin iṣẹ abẹ kindinrin ti wọn ṣe fun un nileewosan UCH, n’Ibadan. Iroyin naa pada jẹ ofege, nitori Ọlaiya funra ẹ jade sita pe oun ko ku o, alaafia loun wa.
Lẹyin abẹwo ọjọ Sannde yii, Mista Latin sọ ọ di mimọ pe oun lọọ ki oṣere ọmọ Abẹokuta naa nile, inu oun si dun pe ara rẹ ti n ya daadaa.
Lati fidi ohun ti wọn fi lọọ ki Ọlaiya mulẹ, akọroyin wa pe Gomina TAMPAN nipinlẹ Ogun, Owolabi Ajasa, lori foonu lẹyin ti wọn ti ile Ọlaiya de, o si ṣalaye pe ki i ṣe aisan kindinrin lo n ṣe ọga awọn, bẹẹ ni ko ṣiṣẹ abẹ ti wọn fi n paarọ kindinrin bawọn kan ṣe n gbe e kaye.
Ajasa sọ pe kinni kan ti wọn n pe ni ‘Kidney stone’ iyẹn okuta ninu kindinrin lo ṣe Ọlaiya, awọn dokita ri okuta kekere ninu kindinrin rẹ, wọn si ṣiṣẹ abẹ rẹ fun un.
O ni iṣẹ abẹ naa lọ nirọwọ-irọsẹ, kinni kan ko ṣe Ọlaiya lẹyin ti wọn ṣe e tan. O fi kun un pe awọn waa ki i gẹgẹ bo ṣe yẹ keeyan ṣabẹwo si ẹni to ṣẹṣẹ n gbadun ni, ki i ṣe nnkan mi-in, awọn si dupẹ pe alaafia ti n de si ara Igwe awọn onitiata, Ẹbun Oloyede.