Jọkẹ Amọri
Ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn agbebọn tun kọ lu awọn eeyan abule Yelwan Zangam, nitosi Fasiti Jos, ti wọn si pa eeyan marundinlogoji nipakukpa.
Niṣe ni awọn agbebọn naa bẹrẹ si i yinbọn leralera mọ gbogbo awọn ara abule naa ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn nigba ti wọn ya bo ibẹ. Bẹẹ ni wọn tun dana sun awọn to wa ninu ile mọbẹ. Nigba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, eeyan marundinlogoji lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ.
ALAROYE gbọ pe ki awọn agbebọn naa too wọ abule ọhun ni wọn ti kọkọ ba biriiji to wọ ibẹ jẹ, ki awọn abule to tun wa nitosi abule naa ma le raaye waa sọ pe awọn fẹẹ gba wọn silẹ.
Bo tilẹ jẹ pe wahala to ti n waye niluu naa, paapaa ju lọ ni ijọba ibilẹ Bassa ti mu ki wọn kede konilegbele ni agbegbe Ila Oorun ati Guusu agbegbe naa, ṣugbọn eyi ko di awọn eeyan naa lọwọ, wọn tun ya wọn abule yii, wọn si fọpọ ẹmi eeyan ṣofo.